- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Àdàwólulẹ̀ ilé ayé-àtijọ́ ọlọ́dún-un 150 fi àìkáràmáìsìkí ìjọba sí àwọn ibi àjogúnbáa Bangladesh hàn

Sàwáwù : South Asia, Bangladesh, Àṣà àti Iṣẹ́-ọnà, Ètò ìjọba, Ìdàgbàsókè, Ìfẹ̀hónúhàn, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́, Òfin, Ọrọ̀-Ajé àti Okòwò
[1]

Ẹgẹrẹmìtì “Jahaj Bari” kí ó tó di àdàwólulẹ̀. Òun ni ilé àkọ́kọ́ àyàgbé ní olú-ìlú Bangladeshi, Dhaka, a kọ́ ọ ní ọdún-un 1870. Àwòrán láti ọwọ́ọ Shakil Ahmed. A fi àṣẹ lò ó.

Ní Dhaka, ilé àjogúnbá ọlọ́gọ́rùn-ún ọdún kan di àdàwólulẹ̀ [2] pátá ní alẹ́ ọjọ́ Ìtunu Àwẹ̀ [3]5, oṣù Òkúdù 2019. Ní nǹkan bíi ọdún-un 1870 ni a kọ́ ilé náà tí ó fẹ́ẹ́ dà bíi ọkọ̀ ojú-omi, tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ń pè ní “Jahaj Bari”, òun sì ni ilé àyágbé àkọ́kọ́ ni olú-ìlúu Bangladesh. Àdàwólulẹ̀ tí a da ilé yìí ti mú kí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn ó sọ ẹ̀dùn ọkàn-an wọn síta lórí àìbìkítà fún àwọn ilé tí ó jẹ́ ohun ìṣúra Dhaka.

Ìròyìn [4] fi yé wípé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà lórí ipò ìyẹn Awami League [5] (AL) gbé ẹ̀rọ tatapùpù wá sí ibẹ̀, wọ́n sì da ilé náà wó. Àwọn tí ó wá ṣiṣẹ́ náà sọ wípé olóríi àwọn, ọmọ ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ (Dhaka-7 [6]) Haji Md. Salim, ti ra ilẹ̀ náà láti fi kọ́ ilé alájà tó pọ̀ sí ibùdó náà. Bákan náà àwọn alátìlẹ́yìn AL sọ wípé ilé àtijọ́ náà kò sí lóríi àwọn ibi àjogúnbá tí ó wà nínú àkọsílẹ̀.

Ní ọjọ́ 13, oṣù Ògún ọdún-un 2018, Ilé-ẹjọ́ Gíga Dhaka pàṣẹ [9]fún àjọ ìjọba tí ó ń rí sí ètò ìdàgbàsókè ìlú ní ìlànà tìgbàlódé ní Dhaka láti máà wó tàbí tún àwọn ilé àjogúnbá tí ó wà ní olú-ìlú náà tó bíi 2,200 kọ́. Jahaj Bari wà nínú àwọn ilé àkọ́pọ̀ Waqf [10] (mortmain [11]) tí kò ṣe é tà. Gẹ́gẹ́ bí [12]alákòóso Bangladesh Waqf Administratioń [13]ṣe sọ, gbígba àṣẹ pọn dandan láti gbé iṣẹ́ sílẹ̀, tà tàbí ṣe àtúnṣe sí ohunkóhun tí ó bá jẹ́ ti Waqf. Èyí kò rí bí ajàfẹ́tọ̀ọ́ AL náà ti ṣe wí, kò sí ohun tó jọ ọ́, kò sí àṣẹ tí ó ní kí wọ́n tà tàbí wó ilé tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí.

Nínú oṣùu Ẹrẹ́nà ọdún-un 2019, a gbé ìgbésẹ̀ kan  [12]láti da ilé náà wó lulẹ̀. Urban Study Group [14], ẹgbẹ́ aṣiṣẹ́ ọ̀fẹ́-tí-kò-ní-èrè tí ó máa ń fi ààbò fún àwọn ohun àjogúnbá Dhaka Àtijọ́ fi ìwé ẹ̀dùn [12] ìdáwọ́dúróo àdàwólulẹ̀ náà ránṣẹ́ sí àwọn tí ọ̀rán kàn, tí ó sì mẹ́nu ba àṣẹ Ilé-ẹjọ́ Gíga.

Síbẹ̀, bí ìwé ìròyìn ṣe jábọ̀ [15], díẹ̀ lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ń yọ̀ fún àdàwólulẹ̀ ilé náà. Wọ́n ò mọ̀ pé ilé náà ti di ẹgẹrẹmìtì, ó sì lè wò lulẹ̀ kí ó wó lù wọ́n—tí í ṣe àpẹẹrẹ àìmọ̀kanmọ̀kàn àwọn ènìyàn sí ìpamọ́ ohun àjogúnbá àti àtìlẹ́yìn fún àtúnṣe sí ilé àtijọ́ tí ó wà ní Bangladesh.

Àjogúnbá Ìṣẹ̀lẹ̀ Àtẹ̀yìnwá —ọ̀rọ̀ tí ò jẹ́ mọ́ nǹkan

Ọ̀pọ̀ ènìyàn l'ó fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àmúdipẹ̀tẹ́lẹ̀ ilé náà. Shuvra Kar [16] kọ sí oríi Facebook:

ঐতিহ্য, ইতিহাস, কৃষ্টি এসব এদেশে গাল ভরা কথা!!

Àjogúnbá , ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá, àṣá jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò já mọ́ nǹkan ní orílẹ̀-èdè yìí!

Òǹkọ̀wé Tania Kamrun Nahar [17] tan ìmọ́lẹ̀ sí ìdí tí kò fi yẹ kí ilé yìí di àdàwólulẹ̀:

তিনতলা ‘জাহাজ বাড়ি’র দোতলায় ছিলো নকশা করা রেলিং, ছাদওয়ালা টানা বারান্দা। আর পুরো অবয়বজুড়ে নানা রকম কারুকাজ। কোণাকৃতির আর্চের সারি, কারুকাজ করা কার্নিশ। কলামে ব্যবহার করা হয়েছিল আয়নিক ও করিন্থিয়ান ক্যাপিটাল। পশ্চিম প্রান্তে আর্চ ও কলামের সাথেও নানারকম অলঙ্করণের ব্যবহার দেখা যায়। সব মিলিয়ে এই ভবনটিতে যে ধরনের অলঙ্করণের ব্যবহার, তা একে এক অনন্য মাত্রা দিয়েছিল। এ ধরনের অলঙ্করণ পুরান ঢাকায় আর কোনো ভবনে দেখা যায় না। সেদিক থেকে এর নান্দনিক গুরুত্বের জন্যই ভবনটি সংরক্ষণ করা প্রয়োজন।

Ilé alájà-mẹ́ta náà “Jahaj Bari” ní àwọn iṣẹ́ ọnà tí ó yàrà ọ̀tọ̀ lára ní ara irin àgbọ́wọ́lé gun àkàsọ̀. Iṣẹ́ ọnà aláràbarà ti orí òrùlé ibi ìbojúwòta gígùn. Ọ̀kanòjọ̀kan ọnà ni ó wà ní ara ilé náà — àwọn àràbarà ọnà abẹ́ àjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òpó ní àwòṣe ọnà ilée ionic àti Corinthian [18]. Ọnà ara ilé náà kọjá àfẹnusọ tí a kò le è rí lára àwọn ilé mìíràn ní àwọn agbègbè àtijọ́ọ Dhaka. Fún ìdí èyí, kò yẹ kí ilé náà di àdàwólulẹ̀.

Ọdún-un 1610 ni Dhaka [19] di olú-ìlúu Bengal, ìyẹn ogójì ọdún sẹ́yìn. Ní sáàa Mughal [20] àti ìjọba amúnisìn British, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé tí a kọ́ ni ó ní ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá àti àjogúnbá ìlú náà kan tí ó rọ̀ mọ́ ọn.

Àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn ilé wọ̀nyí ni ó ti wó láti ọjọ́ pípẹ́. Àwọn tí ó ṣì ń dúró ti di ẹgẹrẹmìtì, èyí á mú kí àwọn kan ó máa lọ (ṣe ayédèrú ìwé láti) gbẹ́sẹ̀ lé ilé wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ kan ni Bara Katra [21], àrágbáramúramù ilé tí ó ní ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí Mir Abul Qasim, Diwan (alága ètò ìṣúná) ti ó jẹ́ ọmọba Shah Shuja Mughul kọ́ ní nǹkan bíi 1644 àti 1646. Ó jẹ́ nǹkan ìbànújẹ́ wípé ilé náà ti ṣe tán, ó lè wó nígbàkigbà látorí àìṣàtúnṣe, àìkáràmáìsìkí ohun àjogúnbá, àti ìbàjẹ́ tí àwọn tí ó gbé ilé láì gba àṣẹ ń fà [22].

[23]

Bara Katra [24]. Àwòṣe ilé kíkọ́ ìbílẹ̀ Àárín gbùngbùn Asian caravanserais [25] ni a fi kọ́ ọ, ó sì ní ọwọ́ọ àwòṣe Mughal náà.  Ragib Hassan ni ó ní àwòrán ní oríi Wikipedia. CC BY 2.5

Muntasir Mamun ti kọ àìmọye ìwé lóríi ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá àti àjogúnbá ìlúu Dhaka. Ó kọ sínú ìwé ìròyìn ìbílẹ̀ẹ Bhorer Kagoj [26]:

গত চার দশক বড়কাটরা ছোটকাটরা সংরক্ষণ করার জন্য কতো আবেদন-নিবেদন করলাম, কেউ শুনল না। আজ সেগুলো ধ্বংস করে ফেলা হয়েছে। প্রতœতত্ত্ব দপ্তর যেখানে লালবাগ কেল্লার দেয়াল ভেঙে ফেলে গাড়ি পার্কিংয়ের জন্য তখন আর কী বলা যায়! মূর্খতার বিরুদ্ধে আর কতো লড়াই করা যায়?

Mo ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn aláṣẹ fún ogójì ọdún tí ó kọjá láti gba àwọn ilé àjogúnbá bíi Bara Katra àti Choto Katra [22] sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó fẹ́ pa ìtàn àtẹ̀yìnwá rẹ́. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn. Kí ni ká sọ? Nígbà tí ẹ̀ka tí ó ń ṣe àkópamọ́ sítám̀pù ti wo ògiri àtijọ́ àmọ̀káyée Lalbagh Fort [27] láti fi ṣe àyè ìgbọ́kọ̀sí, báwo ni a ó ṣe dojú ìjà kọ ìwà òmùgọ̀?

Ilé oníròyìn orí-ayélujára kan ti ṣe àtẹ̀jáde àbájáde  [28]ìwádìí tí ó jinlẹ̀ nípa àìkáràmáìsìkí ìjọba lóríi àwọn ilé àjogúnbá àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó ń gbìyànjú láti da àwọn ilé tí ó kù wó:

ইতিমধ্যেই শাঁখারী বাজারের হেরিটেজভুক্ত ১৪ নম্বর বাড়িটি ভেঙ্গে ফেলা হয়েছে। সুত্রাপুরের বড় বাড়িটির সিংহভাগই ধ্বংস করা হয়েছে। মোগল আমলের স্মৃতিবাহী বংশাল মুকিম বাজার জামে মসজিদ, সিদ্দিক বাজার জামে মসজিদ সংস্কারের নামে ধ্বংস করা হয়েছে। [..] এসব স্থাপনা রক্ষায় সরকারের সুস্পষ্ট নির্দেশনা থাকলেও রাজউক ও ডিসিসির কর্মকর্তারা রহস্যজনক ভূমিকা পালন করেছে। অনেকক্ষেত্রে এদের নীরবতা ঐতিহ্য ধ্বংস সহায়ক শক্তি হিসাবে কাজ করছে।

Ilé tí ó wà ní ipò.14 ní orí ìwé àkọsílẹ̀ àjogúnbá ti di wíwó. Apá kan lára àwọn ilé àwòṣífìlà tí ó wà ní Sutrapur kò ṣe é rí mọ́n. Iṣẹ́ àtúnṣe sí àwọn àjogúnbá ìgbàa Mughal ní mọ́ṣálááṣí Bangshal Mukim Bazar Jam-e àti mọ́ṣálááṣí Siddique Bazar Jam-e ti di ohun ìgbàgbé nítorí ojú àpá ò le è jọ ojú ara, ó ti yàtọ̀. [..] Àmọ́ ṣá, ó ní àṣẹ ìjọba tí ó fi ààbò bo àwọn ilé àjogúnbá, àwọn agbèfúnjọba ti agbègbèe Rajdhani Unnayan Kartripakkha àti Àjọ Ìlúu Dhaka kò ṣe ohun tí ó yẹ kí wọn ó ṣe. Àìṣojúṣe wọn ni ó fà á tí àwọn olóṣèlú olójúkòkòrò ṣe ń gba àwọn ilé àtijọ́ tí wọ́n sì ń dà wọ́n wó lulẹ̀.

Ẹgbẹ́ Urban Study ti ṣe àgbékalẹ̀ ìwọ́de àti àkójọ àwọn ènìyàn tí yóò fi ẹ̀hónú àdàwólulẹ̀ wọ̀nyí hàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gbèrò láti ṣe ìkéde nípa ìdààbò bo àwọn ilé àjogúnbá tí ọ̀rán kàn.

Àwòrán ìsàlẹ̀ yìí ni àwọn ilé àjogúnbáa Bangladeshi tí àdàwólulẹ̀ ń bá:

[29]

Ilée Zamindar [30] àtijọ́ kan ní Nazira Bazar ní agbègbèe Àtijọ́ọ Dhaka ti ń di wíwó lulẹ̀. Àwòrán láti ọwọ́ọ Shakil Ahmed. A lò ó pẹlú àṣẹ.

[31]

Aàfin Nimtali  [32]. Òun ni ibùgbé Gómìnà Dhaka ní ayée Ìjọba Mughal.  Ìloro àbáwọlé ìwọ̀-oòrùn-un ààfin náà nìkan ló ṣì ń dúró. Àwòrán láti ọwọ́ọ Shakil Ahmed. A lò ó pẹlú àṣẹ.

[33]

ShankhaNidhi  [34]। Èyí ni ilé ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn mìíràn ní Dhaka. Láìsí àmójútó, ilé yìí ṣì dúró. Àwòrán láti ọwọ́ọ Shakil Ahmed. A lò ó pẹlú àṣẹ.

[35]

Northbrook Hall . tàbí [36] Lal Kuthi – Fritz Kapp ni ó ya àwòrán yìí ní ọdún-un 1904. Ilé yìí ṣì ń dúró lónìí. Oríi Wikipedia ni àwòrán yìí wà. Ojú Òde