- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Brazil, ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin di ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba

Sàwáwù : Latin America, Brazil, Àyíká, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìbò, Indigenous, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Obìrin àti Akọtàbábo, Òfin
UN/Screenshot [1]

Joenia ni ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil. Àwòrán: Àwòrán tí wọ́n yà nínú fídíò kan láti ọwọ́ọ United Nations Web TV.

Ní ọdún-un 1997, Joenia Wapichana di obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin [2] ní Brazil. Lẹ́yìn ọdún kọ́kànlá, òun ni ọmọ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó gbẹjọ́rò ní ilé-ẹjọ́ gíga jùlọ [3]. Ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2018, Joenia tún gbajúmọ̀ sí i nígbà tí ó di ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí wọn yóò yàn sípò nínú ìgbìmọ̀ ìjọba. [4]

Ìbòo 8,491 [5] tí wọ́n dì fún un ni wọ́n fi yàn án sípò kan nínúu mẹ́jọ tí ó tọ́ sí ìpínlẹ̀ Roraima tí ó ti wá. Ìgbà kan ṣoṣo tí Brazil ní ọmọ ìbílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba ni ọdún-un 1986 — Mario Juruna [6], tí ó wá láti ẹ̀yà Xavante, wọ́n yàn án sípò ní ọdún-un 1983.

A bí Joana sínú ẹ̀yà Wapichana, ó lọ sí Boa Vista tí ó jẹ́ olú-ìlú Roraima nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ. Ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ọ rẹ̀ nínú ìmọ̀ òfin bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn oníṣirò kan, ó sì sọ ọ́ nínú  ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan láìpẹ́ [7], pé òun ṣetán ní ilé-ẹ̀kọ́ ní ọdún kan ṣáájú ìgbà tí ó yẹ kí òun ṣetán tí òun sì gbé ipò karùn-ún nínúu kíláàsìi rẹ̀ àti láàárín-in àwọn ọmọ ọlọ́lá ní Roraima.

Ní oṣù Ọ̀pẹ ọdún-un 2018, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ tí wọ́n dìbò yàn, Joenia gba àmì ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ UN fún ìjàfẹ́tọ̀ọ́ ẹ̀dá [8] lórí àṣeyọrí tí ó ṣe nínú ìpolongo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀. Wọ́n ti fi àmì-ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ yìí kan náà fún Nelson Mandela àti Malala rí.

[9]

Joenia Wapichana níbi tí ó ti ń gbè lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìbílẹ̀ kan ní ilé-ẹjọ́ gíga jùlọ. Àwòrán: Àwòrán tí wọ́n yà nínú fídíò YouTube ilé-ẹjọ́ gíga jùlọ ti Brazil.

Ibi tí àyípadà ti bẹ̀rẹ̀

Joênia ṣe àfikún ìtàn ní ọdún-un 2008 nígbà tí ó gba ẹjọ́ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ márùn-ún kan rò, pé kí wọn ya ilẹ̀ẹ wọn [10] sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ abínibí, irú òfin tí yóò fún àwọn abínibí ilẹ̀ náà ní ẹ̀tọ́ láti pàṣẹ lórí àwọn ilẹ̀ ìlúu wọn.

Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ tí ó gbè lẹ́yìn àwọn ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ náà tí wọ́n ti wá di òǹnilẹ̀ kánrin-kése fún àwọn ilẹ̀ abínibí tí ó tóbi jù ní Brazil — ilẹ̀ẹ Raposa Terra do Sol [10], tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Roraima.

Bẹ́ẹ̀, Jair Bolsonaro tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ ní àkókò náà ti fi ìwọ̀sí lọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìbílẹ̀ kan tí ó wá sí ibi gbígbọ́ ìdájọ́ nípa ìyàsọ́tọ̀ Raposa Terra do Sol ní ìyẹ̀wù àwọn igbá-kejì. Bolsonaro sọ̀rọ̀ [11] báyìí ní ọjọ́ náà pé “ó yẹ kí o jáde síta láti lọ jẹ koríko pẹ̀lú àwọn alálẹ̀ẹ yín”.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ó jáwé olúborí nínú ìdìbò 2018, Bolsonaro tún mú ọ̀rọ̀ Raposa Terra do Sol bọnu gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ agbègbè ìbílẹ̀ tí ó yẹ kí àwọn jẹ àǹfààní ètò ọrọ̀-ajée rẹ̀. Ó sọ [12] fún àwọn akọ̀ròyìn pé:

É a área mais rica do mundo [em minerais]. Você tem como explorar de forma racional. E no lado do índio, dando royalty e integrando o índio à sociedade.

Ó jẹ́ agbègbè kan tí ó lọ́rọ̀ jù ní àgbáyé. Èèyàn lè jẹ àǹfààní rẹ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Nípa ti àwọn ọmọ bíbí ibẹ̀, à á fún wọn ní ohun tí ó tọ́ sí wọn, à á sì dà wọ́n pọ̀ mọ́ àwùjọ.

Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, pẹ̀lú ọ̀dà pupa lójúu [13]rẹ̀ [13], ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ẹ̀yàa rẹ̀ ni Joenia lo èdè Portuguese àti ẹ̀ka-èdèe rẹ̀ láti rán àwọn adájọ́ létí pé bíi mílíọ̀nù dọ́là US lọ́nà mẹ́ta ni ó ń kárí àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí láìsí pé wọ́n kópa nínú ètò ọrọ̀-ajée Brazil. Ó ní “wọ́n ń sọ̀rọ̀ bà wá lórúkọ jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìyàtọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀yà pẹ̀lúu wa ní ilẹ̀ẹ wa”.

Àwòrán: Àjọ tí ó ń rí sí ààbò gbogboògbò, CC 2.0

Alátakò tí kò ṣe é borí

Bí ó ṣe ń gbaradì láti gba ìjókòó rẹ̀ nínú ìgbìmọ̀ ìjọba gẹ́gẹ́ bí alátakò fún ìjọba Bolsonaro, ó sọ fún àwọn akọ̀ròyìn Folha de São Paulo [14], tí ó jẹ́ ilé iṣẹ́ oníwèé ìròyìn tó gbajúgbajà ní orílẹ̀-èdè pé:

Por que ele persegue tanto os povos indígenas? Qual é a razão de todo esse ódio e de querer retroceder tanto?

Temos turismo, medicinas tradicionais, uma vasta biodiversidade na Amazônia. A gente tem de mudar esse discurso de que somos empecilho ao desenvolvimento, que estamos prejudicando A ou B. Temos de fazer com que sejamos nós os protagonistas também.

Kí ló dé tí ó [Bolsonaro] ṣe ń ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tó báyìí? Kí ni ìdí fún ìkórìíra àti òǹgbẹ fún ìṣubúu wa?

A ní ètò ìrìnàjò ìgbafẹ́, òògùn ìbílẹ̀ àti àwọn ohun mèremère tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ káàkiri ilẹ̀ẹ wa. A nílò láti ṣe àyípadà ìgbàgbọ́ pé à ń ṣe ìdíwọ́ fún ìdàgbàsókè tàbí pé à ń ṣe ìpalára fún ẹnikẹ́ni. Àwa náà ní láti di aṣíwájú fún ara wa…

Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ tí ó ń lọ

Ìgbìmọ̀ Brazil gba ipò ní oṣù Èrèlé 2019, Joênia sì bẹ̀rẹ̀ sáà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdarí ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ [15], Rede Sustentabilidade (tí ó túmọ̀ sí Ẹgbẹ́ Alágbèéró lédè Portuguese) ní ìyẹ̀wù àwọn igbá-kejì ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré. Olùṣàkóso fún ètò àyíká tẹ́lẹ̀ rí Marina Silva [16], tí orúkọ rẹ̀ gbajúmọ̀ nínú ìjàfẹ́tọ̀ọ́ agbègbè ni ó dá Rede sílẹ̀ pẹ̀lú bí ó ti ṣe fìdírẹmi tó nínú ètò ìdìbò ààrẹ lẹ́ẹ̀mẹ́ta léraléra.

Lẹ́yìn àjálù ìdídò [17] ní Brumadinho, tí ó pa àwọn èèyàn tí ó lé ní 160, tí ó sì mú ìbàjẹ́ bá gbogbo ayé [18] tí ó wà ní odò Paraopeba, Joenia ṣe àgbékalẹ̀ àkọsílẹ̀ àbá òfin rẹ̀ àkọ́kọ́ [19], tí ó ń ka àwọn ọ̀ràn tí ó ń ṣe ìpalára fún agbègbè àti ìlera pẹ̀lú ẹ̀mí àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí “ọ̀ràn ńlá” tí ó ní ìjìyà tí ó pọ̀ nínú.

Ní ó-ku-ọ̀la tí yóò gba ipò, arábìnrin inú ìgbìmọ̀ náà sọ fún Folha de Boa Vista [20], ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìbílẹ̀ kan tí ó ti ìpínlẹ̀ẹ rẹ̀ wá pé àbá òfin náà ń dojúkọ ìwà àìbìkítà àwọn iléeṣẹ́ àdáni sí agbègbè:

Nos preocupa a política governamental de enfraquecer ainda mais os mecanismos criados para defender o meio ambiente saudável, previsto em nossa Constituição, e os impactos sociais, como, por exemplo, o licenciamento ambiental, diante da falta de responsabilidade das empresas e do baixo poder de fiscalização do Estado.

Ohun tí ó kàn wá ni ètò ìmúlò tí ìjọba fi ń ṣe àdínkù agbára àwọn àtòpọ̀ ẹ̀rọ tí a ṣẹ̀dá láti dáàbò bo àyíká tó ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ìwé òfin àti àwọn ipa tí ó ń kó láwùjọ. Fún àpẹẹrẹ [lára àwọn àtòpọ̀ ẹ̀rọ yìí], a ní ètòo gbígba ìwé àṣẹ ní àwọn agbègbè yìí [tí ó ń bá wa dènà] àìlègbẹ̀rí àwọn iléeṣẹ́ jẹ́ àti àìtó agbára ìjọba láti kápáa wọn nínú ìpínlẹ̀ náà.
.

Nínú ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ pẹ̀lú BBC [21], Joenia sọ pé ohun tí ó ṣe pàtàkì sí òun jùlọ nínú ìgbìmọ̀ náà ni ìyàsọ́tọ̀ àwọn ilẹ̀ abínibí:

Se por um lado há meia dúzia de ruralistas, por outro há uma população de minorias que se sente representada por mim ali. É uma população que precisa de representação. A política velha é formada por pessoas que só pensam em benefícios individuais. Eu vou levar valores coletivos.

Tí o bá ní èèyàn ńláńlá mẹ́fà ní ọwọ́ kan, tí ọwọ́ kejì sì ní àìmọye àwọn èèyàn tí wọn ò jámọ́ nǹkan tí wọ́n ń rí mi gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn níbẹ̀. Wọ́n jẹ́ ọ̀wọ́ àwọn tí ó nílò aṣojú. Ètò ìṣèlú àtẹ̀yìnwá wáyé nípasẹ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń ro ohun tí ó máa jẹ́ èrèe tiwọn níbẹ̀, èmi máa mú iyì tí ó kárí wá.