Twitter @DigiAfricanLang 2019

Bẹ̀rẹ̀ láti ogúnjọ́ oṣù Ẹrẹ́nà títí di òpin ọdún-un 2019, àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá á máa ṣe ‘ọ̀ọ̀wẹ̀’ láti ṣàkóso aṣàmúlò Túwítà @DigiAfricanLang ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé, aṣàmúlò tuntun náà á máa ṣàfihàn ipa tí ìmọ̀-ẹ̀rọ ń kó nínú ìgbélárugẹ àti ìgbéǹde àwọn èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀. Èròńgbà kan gbòógì fún ìpolongo orí Túwítà náà ni láti lè ṣe ìdámọ̀ àti àfihàn ìfọkànsìn àwọn ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọ́n ń ṣàmúlò gbogbo àwọn gbàgede orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá àti ayélujára láti gbé èdè àti àṣàa wọn lárugẹ, tí wọ́n sì ń ṣe ìfàmọ́ra ìran tuntun tí yóò máa sọ èdèe wọn.

Nínú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Yorùbá Names Project àti Global Voices lédè Yorùbá, Rising Voices máa ṣe àkóso ìkópa ìpolongo àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ èdèe ilẹ̀ Adúláwọ̀ orí ayélujára tó lé ní ogójì káàkiri àgbáyé, ní kòńgẹ́ pẹ̀lú ayẹyẹ Àyájọ́ Èdè Ìbílẹ̀ Àgbáyé International Year of Indigenous Languages.

Gẹ́gẹ́ bí àlejò orí Twitter, àwọn akópa ìpolongo náà á sọ̀rọ̀ nípa àfojúsùn wọn àti ihà tí wọ́n kọ sí èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀, pẹ̀lú ìtàn wọn, ìlò wọn lórí ayélujára àti ojú ayé, ìdojúkọ wọn àti àwọn ìlànà àmúlò tuntun tí wọ́n ní fún ìgbéǹde èdè náà. Bí ìmọ̀-ẹ̀rọ ṣe ń kó ipa pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó ń ṣe ìdènà fún pàtàkì àwọn èdè abínibí.

Ìpolongo yìí yóò f'ara jọ èyí tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní Latin America pẹ̀lú aṣàmúlò Twitter @ActLenguas.

Lára àwọn àlejò tí a ti ṣètò láti kópa nínú ìpolongo náà ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú èdè Yorùbá, Igbo, Swahili àti Twi nípasẹ̀ àwọn gbàgede bí i Wikipedia, àwọn ìkọ́ni àti ìṣeré orí ẹ̀rọ-alágbèéká, iṣẹ́ títú ìmọ̀ èdè, ìwé atúmọ̀ èdè orí ayélujára, ìfèdèṣètò àwọn ohun èlò ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti àwọn ìpolongo lórí àwọn gbàgede orí ayélujára.

Iṣẹ́ orí gbàgede àwùjọ ayélujára yìí wáyé nípa ìṣírí láti ara àwọn àtinúdá bí i @IndigenousX ti Australia, tí olùdásílẹ̀ rẹ̀ Luke Pearson pèsè ìtọ́sọ́nà pàtàkì ní àwọn ipele ìṣètò. Àkóso aṣàmúlò Instagram ti Global Voices náà ń lọ, tí àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ n gbaṣẹ́ṣe lọ́wọ́ ara wọn náà, tí ó sì ti jẹ́ ọ̀nà pàtàkì fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ káàkiri àgbáyé láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ibi tí wọ́n ń gbé.

Jọ̀wọ́ ṣe àyẹ̀wò ètò ìsàlẹ̀ yìí fún àwọn tí ó ti darapọ̀ mọ́ wa láti sọ̀rọ̀ nípa ìtàn-an wọn. À ń gbèrò láti ní àkọsílẹ̀ búlọ́ọ̀gù kúkúrú nípa àwọn “àlejò” náà lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ètò

March 20-26:

Kọ́lá Túbọ̀sún (@kolatubosun)

Linguist, lexicographer at @oxfordwords. Founder @yorubanames. Writer at @ktravula etc. Morland Writing Scholar 2019. Author “Edwardsville by Heart” (poetry).

March 27-April 3:

Ọmọ Yoòbá (@yobamoodua)

Olùfẹ́ àṣà. Ọmọ Yorùbá àtàtà. Ọmọ Oòduà t'ọkàntọkàn #Teacher ? @tribalingual #localization #translator ?@L10nLab @gvyoruba #Anthropologist #Farmer #Author

 

April 4-10:

Ruben Hilare (@Zaituni_Njovu)

CEO|Technologist|Digital Security Trainer| @ZainaFoundation

 

April 17-23:

Ezeibe Emeka Francis (@emekaezeibe)

Transport/Logistics Consultant #FreelanceFootballWriter,#NPFL Initiator: @Umu_igbo l SELL QUALITY ADIRE MATERIALS #BUSINESSMAN #GoodGovernance #SUSTAINEDBYGRACE

April 24-30:

Adebayo Adegbembo (@technobayo)

Dreamer, Writer, Teacher, Programmer & Cultural Evangelist for Àșà (@genii_games). http://bit.ly/2h6y9Pa

 

May 15-21:

Damilola Adebonojo (@iyayoruba )

Yorùbá Language Specialist | Tutor | Critic | Contributor & Yorùbá Translator at Global Voices | Transcriber | Culture Enthusiast | Founder of Alámọ̀já Yorùbá

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.