- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Olórí orílẹ̀-èdè Azerbaijan tàkùrọ̀sọ àkọ́kọ́ ní orí amóhùnmáwòrán lẹ́yìn ọdún 15 ní orí àlééfà. Ó lè lo ọ̀nà mìíràn.

Sàwáwù : Central Asia & Caucasus, Azerbaijan, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn àti Ìròyìn-kíkọ, Ìṣèlú

Ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ Ààrẹ Ilham Aliyev àti amóhùnmáwòran REAL TV ní Oṣù Èrèlé 12. Àpá àwòrán wá láti REAL TV ẹ̀rọ-alátagbà
YouTube channel [1].

Ẹ̀rìn mélòó ló yẹ kí ààrẹ orílẹ̀ èdè ní ìtakùrọ̀sọ pẹ̀lú ilé ìgbéròyìn jáde tí ìlúu rẹ̀? Ẹẹ̀kan l'ọ́sẹ̀? Ẹẹ̀kan l'óṣù? Àwọn olórí orílẹ̀ èdè afipá ṣe ìjọba máa ń ṣe ìtakùrọ̀sọ pẹ̀lú àwọn ilé ìgbéròyìn jáde ní èèkàn l'ọ́dún tàbí kí ó kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí kọyọyọ ní Azerbaijan. Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, Ààrẹ Ilham Aliyev, tí ó di olórí ilẹ̀ Azerbaijan ní Oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2003, ṣe ìtakùrọ̀sọ alákọ̀ọ́kọ́ọ rẹ̀ pẹ̀lú ilé ìṣẹ́ amóhùn-máwòrán ti ìlúu rẹ̀.

Ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò oníwákàtí kan ọ̀hún tí ó wáyé lọ́jọ́ 12 oṣù yìí, pẹ̀lú oníròyìn ìjọba Mirshahin Aghayev — tí a ti mọ̀ [2] tẹ́lẹ̀ rí fún ìdúróṣinṣin aìfi òlò p'ohùn — di gbígbésáfẹ́fẹ́ [1] ní ilé ìṣẹ́ amóhùn-máwòrán aládàáni agbè fún ìjọba REAL TV.

Ó gbọn òǹgbẹ ni Azerbaijan, ilẹ̀ tí àwọn ará ìlú ti máa ń gbọ́ kí Aliyev sọ̀rọ̀ lórí afẹ́fẹ́, àmọ́ tí wọn kò sì rí i rí kó tàkùrọ̀sọ pẹ̀lú oníbèèrè. Kódà ìṣàmúlò Twitter Aliyev dà gẹ́gẹ́ bí wèrè aládàásọ̀rọ̀ [3] ju ìgbìyànjú ìbá ará ìlú sọ̀rọ̀ lọ.

Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò ọ̀hún jẹ́ àkọ́ṣe tí ó kọyọyọ. Púpọ̀ àwọn tí ó wà lórí ẹ̀rọ ayélujára gbogbo sọ̀rọ̀ lórí aìkọbì-ara sí bí ààrẹ ṣe gbé ara rẹ̀, bí ó ṣe múra àti àwọn kókó tí ilé ìṣe ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ìjọba sọ̀rọ̀ lé lórí.

Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé kò pọn dandan kí Aliyev ṣàfihàn ara rẹ̀ bí ó ṣe tó — Azerbaijan kòì tí ì dìbò tí kò sí kọ́mí-n-kọ́họ lẹ́yìn ọdún 37 tí ó ti gba òmìnira — kíni ó mú u ṣe èyí?

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo Ààrẹ Ilham Aliyev's pẹ̀lú REAL TV ní ọjọ́ 12, oṣù Èrèlé. Àwòrán láti orí ẹ̀rọ-alátagbà YouTube ti REAL TV.

Àwọn kókó ìtakùrọsọ ọ̀hún dá lórí — ìjàkú akátá pẹ̀lú Armenia lóríi Nargono- Karabakh, iṣẹ́ ìlú, àtúnṣe sí ètò ọrọ̀ Ajé, àti ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Aláṣẹpọ̀ Eurasian àti Ẹgbẹ́ Aláṣẹpọ̀ Europe. A kò rí ohun tuntun kan gbámu.

Lẹ́yìn ìgbà tí fídíò [1] ọ̀hún gba kòbákùngbé ìjábọ̀ bíi “Kọ̀wé fipò sílẹ̀” àti “A kò fẹ́ àlọ́ atanijẹ mọ́” pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìní ìfẹ́ràn ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí a gbé e sórí ayélujára, ìkànnì REAL TV ní oríi YouTube ti ìsọsí pa.

Olóṣèlú alátakò Azer Gasimli sọ [4] pé ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò ọ̀hún fi hàn pé “ìfoyà ti dé bá” ìjọba láàárín bí àwọn ará ìlú ò ṣe gba ti wọn àti ọ̀rọ̀ ajé ìlú tí ó ń ṣ'òjòjò.

Mo wo ìtàkùrọsọ àkọ́kọ́ tí Ilham Aliyev ṣe pẹ̀lú oníròyìn ilẹ̀ yìí kan. Mo rò pé kò mọ́gbọ́n dání láti sọ tàbí kọ nǹkan kan l’ ésì si ohun tí Ààrẹ sọ. Nítorí pé a ti ń fún un l'ésì fún ọdún pípẹ́. Kò sí hóró òótọ́ kán nínú ìtàkùrọsọ ọ̀hún. Ààrẹ àti oníròyìn ọ̀hún rán mi l'étí nípa “ọkọ̀ tó léfòó lórí irọ́”. Ní àkótán: ara ò rọ ìjọba!

Habib Muntazir, aládàádúró oníròyìn kan fi ẹ̀dùn ọkàn-an rẹ̀ hàn pé ìtàkùrọsọ ọ̀hún kò gbóòkàn [5]:

Nǹkan kan ṣo tí mo gbọ́ ni “Ìyá àgbà Saray”. Ó dá mi lójú pé ” Ìyá àgbà” yìí yóò ṣòro tí ó wúni lórí ju Ilham Aliyev lọ.

Ìfakùn ọ̀rọ̀ “Ìyá àgbà Saray [6]” tí Muntazir mẹ́nubà dá lórí àbẹ̀wò ìbánidárọ tí Aliyev bá lọ sí Agbègbè Shamakhi tí Azerbaijan, níbi tí ìporùrù ayé [7] tí bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìgbé jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, tí ọ̀kan nínú rẹ̀ jẹ́ ti obìrin ọlọ́mọdún 92 tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Saray.

Ajábọ̀ iṣẹ́ ìjọba ti fúnpá lórí ìpàdé tí Aliyev ní pẹ̀lú Saray, ẹni tí ó ti gba oríyìn gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe rere fún ìfaradà àti ìgbàgbọ́ tí ó ní sí ọjọ́ iwájú orílẹ̀-èdè Azerbaijan lẹ́yìn-in ìṣẹ́lẹ̀ náà.

Ilham Aliyev pàdé Ìyá àgbà Saray. Àwòrán láti qafkaz.info [8].

Bí a ṣe lè ri lára ìtú ìmọ̀ ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ REAL TV [6] l'órèfé, Aliyev sọ àsọdùn ọ̀rọ̀ nínú ìgbóríyìn fún arúgbó ọ̀hún, bí ò tí ṣe perí rẹ ní sísẹ̀ntẹ̀lé:

Irú ìyá àgbà àti àwọn ìyá, gẹ́gẹ́ bíi Ìyá àgbà Saray ti ń ṣakitiyan ìpamọ́ àwọn ìṣe orílẹ̀ wa àti ẹ̀mí-àìrí fún àìní ye ọgọ́rùn-ún ọdún. Gbogbo obìnrin Azerbaijan ni ó fẹ́ fi ìwà jọ ìyá àgbà Saray. Wò ó, obìrin ọmọ ọdún 92 èyí tí ilé rẹ̀ ti di ìlẹ̀ẹ́lẹ̀, ìrètí gidi wo ló tún wà fún un mọ́! Ìyá àgbà Saray ní ìfọkàntẹ̀ pé ìjọba yóò dúró tì òun. Kámáparọ́, nínú ìrìnàjò kékeré lọ sí Shamakhi, n kò rò ó tì tẹ́lẹ̀ pé n ó ṣe àlábàpáàdé Ìyá àgbà Saray. Mo yẹ àwọn ilé tí ìporùrù ilẹ̀ ọ̀hún bà wò fínnífínní, mo sì rí àrító ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ tí mo rí Ìyá àgbà Saray, àrídájú mi lórí bí àwọn ọmọ Azerbaijan ṣe ṣ'èèyàn sí l'ékún sí i. Àwọn ọmọ ilẹ̀ wa á máa mú ìwúrí báni. Ó wà nínú ìṣòro; ilée rẹ̀ ti wó. Ó jọ pé kò mọ̀ pé ẹnìkan yóò wá ṣe ìrànwọ́ fún òun. Kò mọ̀ bóyá ilé òun yóò dí àtúnkọ́ tàbí wọn yóò dà á wó pátápátá kọ́ òmíràn. Àwọn ìyá àgbà bíi Saray ní ẹ̀mí ìforítì òun ìlọra tí ó mú àwọn ọmọ Orílẹ̀ Azerbaijan yàtọ̀.

Oníròyìn aládàádúró mìíràn, Sevinc Osmangizi, fi ṣe àgbékalẹ̀ ìpè [9] kan ní oríi YouTube tí ó ń pè fún ìda-ọ̀rọ̀-wo lórí ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwo ọ̀hún lẹ́yìn tí Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ parí. Àwọn tí wọ́n wò ó sọ àwọn nǹkan tí kò tẹ́ wọn lọ́run, wón sì tún pè fún àyípadà.

Ọ̀kan ní:

N kò le è wo ìfọ̀rọ̀wọ́rọ̀ náà ju ibi mo wò ó dé lọ, mo sì pa ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán. Nítorí pé, òfé lásán ni olùbéèrè Mirshahin Aghayev àti ìbéèrè rẹ̀. Àdéhùn wọn kò wúlò fún wa mọ́. Èké àti irọ́ wọn ti sú àwọn èèyàn. Àwọn ará ìlú ń fẹ́ ohun tuntun àti àtúntò tòótọ́.