Jẹ́ kí àwọn òkú ó sọ ìtàn nípa Hong Kong

Òpópónà Ilé-ìsìn òrìṣà, Yau Ma Tei, Hong Kong. ÀWÒRÁN: David Yan (CC BY 2.0)

Ìkìlọ̀: ìròyìn yìí ní àwọn àwòrán tí ó ń ṣe àfihàn ikú àti  ipá. Medium ti ṣe àtẹ̀jáde ẹ̀dàa ìròyìn yìí ṣáájú èyí.

Bí o bá ti rìnrìn àjò lọ sí Hong Kong, o ṣe é ṣe kí o dé Yau Ma Tei, agbègbè ọjà alẹ́ tí ó jẹ́ ìlúmọ̀nánká níbi tí àwọn ènìyàn ti máa ń lọ ra ọjà àti oúnjẹ ẹ̀gbẹ́ẹ títì. Yau Ma Tei jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè tí èró pọ̀ sí jù lọ ní Hong Kong.

Láti ọdún-un 2016, ẹ̀ka- ìlú náà ti di ibùdó fún  “20,000 ọ̀nà láti gbà kú ní Yau Ma Tei”, ìtọ́nà “ìrìnàjò afẹ́ ìpànìyàn” tí Melody Chan àti èmitìkarami ṣe olùdásílẹ̀, tí ó ti ń gbé àdúgbò náà fún ọdún púpọ̀. Nípasẹ̀ ìrìnàjò afẹ́ náà, a fẹ́ mọ bí ayé àti ìgbé ayé ṣe rí ní Hong Kong.

Ìrìnàjò afẹ́ ojúnà oní kìlómítà 1.5 náà lọ láti arẹwà àti gúúsù Yau Ma Tei, àti ìrìnàjò dé ibi tí a ti pa ènìyàn 12 ní àárín-in wákàtí méjì. A bẹ̀rẹ̀ ẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ètò Halowíìnì láti kó owó jọ fún ilé-iṣẹ́ ìbílẹ̀ kan. Èsì tí a gbà dára tó bẹ́ẹ̀ ni ó mú wa tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò alẹ́ nínú oṣù  tí yìnyín bá ń bọ́ tí ojú ọjọ́ bá tútù. Oníṣẹ́ ìlú ni àwọn amọ̀nà, olùkọ́, oníṣègùn àti àwọn onímọ̀ mìíràn. Bí a bá kà á ní ẹníméjì, ó ti tó ènìyàn 500 tí ó ti ṣe ìrìnàjò náà.

Àwọn ọ̀ràn ìpànìyàn tí a yàn wáyé ní àárín-in ọdún-un 2012 to 2016. Nínú ìwé ìròyìn ni a ti ṣa àwọn ìròyìn àti àkọsílẹ̀ láti ọwọ́ọ ilé ẹjọ́ Oníwàádìí-ẹni-tí-ó-kú.

Ní ìsàlẹ̀ ni àwòrán-eré ránpẹ́ ìrìnàjò afẹ́ ọdún-un 2017 ní oríi YouTube:

Ó súnmọ́, síbẹ̀ ó jìnà 

Iye ènìyàn tí ó ń gbé ní ilẹ̀-tí-omí-fẹ́rẹ̀ẹ́-yíká Kowloon tó bíi èèyàn 40,000 ní orí ìwọ̀n kìlómítà kọ̀ọ̀kan, àti bí i ènìyàn 20,000 ni ó ń gbé Yau Ma Tei. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńláǹlà ni a pín sí kéékèèké. Àwọn ènìyàn ń gbé súnmọ́ ara wọn, àmọ́ síbẹ̀, wọ́n jìnà sí ara wọn.

Àìmọye àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìrìnàjò afẹ́ náà jẹ́ àgbàlagbà. Bàbá arúgbó kan pa ara rẹ̀  nígbà tí ó bẹ́ láti ojúu fèrèsé ilé alájà-mẹ́rin pẹ̀lú okùn tí ó so mọ́ ọrùn.

Òkúu rẹ̀ ń fì ní ìta ògiri ilé náà ní títì ní àárín alẹ́, àmọ́ kò sí ẹni tí ó se àkíyèsí àfi ní ìgbà tí ó di fẹ̀ẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn alùgbé ilé òdì kejì ṣí fèrèsée wọn.

Òmíràn ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà méjì tí a bá òkúu wọn nínú ilé, ọ̀kan kú ikú ebi. Àsẹ̀yìnwá ni ó tó yé wípé ọkọ náà ni ó ṣe olùtọ́jú aya, ẹni tí ó arán ń ṣe. Ọkọ náà kọsẹ̀ nínú yàrá ìgbàlejò, ó sì kú, ebí sì ṣe wẹ́rẹ́ pa ìyàwó sí orí ibùsùn. Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ wípé kò sí ẹni tí ó fura sí irú ìgbé ayé ìjìyà àwọn àgbàlagbà méjì.

Gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn ọdún-un 2016, mílíọ̀nù èèyàn 1.16 million ni ọmọ ọdún 65 àti jù bẹ́ẹ̀ lọ ní Hong Kong— ìyẹn 15.9 ìdá gbogbo ènìyàn. Ẹgbẹ̀rún 150 àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ó ń dá gbé. HK$5,780 (US$720) ni owó oṣù àwọn àgbàlagbà tí í ṣe òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì ní ọdún-un 2016 — àti owó ìrànwọ́ ìjọba lápapọ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, owó oṣù tí ó kéré jù lọ nínú tó HK$16,800 (US$2,200) dollars.

Àmọ́ gbígbé pẹ̀lú ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ kò kan ti ìtìlẹyìn. Ìjàmbá oríṣi ni ó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹbí ní ìlú, pàápàá jù lọ ní àárín àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́.

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé, ọmọdébìnrin ọmọ ọdún 15 ni olóògbé tí ó máa ń múra bí ẹ̀dá-inú ìtàn tí a mọ̀ sí cosplay. Ó f'akọyọ nínú ẹ̀kọ́ọ rẹ̀ àmọ́ ó bá ẹbíi rẹ̀ ní gbólóhùn asọ̀ nítorí olólùfẹ́ẹ rẹ̀. Àbálọ àbábọ̀, ó kúrò ní ilé-ìwé, ó sì di ẹni-àpẹẹrẹ àwòrán láti so ẹ̀mí àti ara ró. Ẹni tí ó ṣiṣẹ́ fún tí ó san owó ọ̀yà HK$500 dollars (US$65) fún un ni ó pa a.

Òmíràn jẹ́ òkú ọmọ-ọwọ́ kan tí ìwọ́ọ rẹ̀ ṣì wà ní a ara rẹ̀, tí obìrin kan tí ó ń ṣe ìmọ́tótó ìbùdókọ̀ abẹ́-ilẹ̀ ní Yau Ma Tei bá nínú àpò kan. Lẹ́yìn ìwádìí, àwọn ọlọ́pàá ṣe àrídájú wípé ọmọ-ọ̀dọ̀ kan láti ilẹ̀ òkèèrè tí ó ń bẹ̀rù wípé ọ̀gá òun yóò lé òun ni ẹnu iṣẹ́ bí ó bá mọ̀ wípé òun ní oyún ni ìyáa rẹ̀. Obìrin náà jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n.

Ní abala ìrìnàjò afẹ́ yìí, amọ̀nà ṣe ìbéèrè: ṣé àwọn ọ̀gá obìnrin náà kò jẹ̀bi bí? Kò sí bí ó ṣe lè ṣẹlẹ̀ kí wọn ó máà mọ̀ wípé ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ fún wọn ní ojúmọ́ ní oyún ní inú. Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó wà ní Hong Kong ju 370,000 lọ, òfin ṣì fi àyè gbà wọ́n kí ó máa gbé nínú ilé ọ̀gáa wọn.

Èyí ni àyè fi sílẹ̀ láti lè rí wọn bá sùn bí wọn bá ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí púpọ̀, láì jẹun tí ó ṣe ara ní oore, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Lẹ́yìn ọdún kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé, ọmọ-ọ̀dọ̀ ilẹ̀-òkèèrè mìíràn gba ìdádúró ní ẹnu iṣẹ́ fún oyún tí ó ní. Ó gba obìnrin náà ní ọdún méjì gbáko nílé ẹjọ́ láti jà fún ìdádúró láì bá òfin mu ní ẹnu iṣẹ́.

Ìpànìyàn ní àárín àwọn ènìyàn 

Ọ̀gọ̀rọ̀ ìpànìyàn ní Yau Ma Tei jẹ́ ẹsẹ̀ tí ó ti ọwọ́ àwọn ènìyàn fún ra wọn wá, tí ó jẹ́ ẹsẹ̀ tí wọn kò gbèrò tàbí pa ète rẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ sì ṣe àṣìṣe.

Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ tí ọkùnrin kan pa ẹ̀gbọ́n-ọn rẹ̀ ọkùnrin ní ìta gbangba ní ojúu títì pẹ̀lú ọbẹ̀ ìwọ̀n ínṣì mẹ́sàn-án tí ó wọ inú ẹ̀dọ̀ fóró ẹ̀gbọ́n-ọn rẹ̀ lọ. Ẹ̀bùn ni ó yẹ kí ọbẹ̀ náà jẹ́ fún ẹ̀gbọ́n náà.

Apànìyàn kan takú sí ibi ìpànìyàn lẹ́yìn tí ó pa ènìyàn tán; òmíràn fi ìwé pẹlẹbẹ ìdánimọ̀ọ rẹ̀ gba iyàrá tí ó tọ́jú òkú ẹni tí ó pa sí.

Ìpànìyàn mìíràn wáyé ní ilé ìtaja-ohun-èlò-inú-ilé. Ẹ̀rọ-ayàwòrán amóhùnmáwòrán ká ìṣẹ̀lẹ̀ náà sílẹ̀. Onírìn àjò ìgbafẹ́ tí ó ń lo ìwé-ìrìnnà Orílẹ̀-èdè Canada ni apànìyàn náà, ẹni tí ó gún òǹtajà ìsọ̀ náà nígbà tí òǹtajà bíi léèrè ìdí tí ó fi kó ọjà láì san owó.

Àlábàápàdé àwọn ẹ̀mí àti òjìjíi wọn 

Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Àwọn kan kópa nítorí wọ́n fẹ́ rí àrídájú; àwọn mìíràn rí i bí ọ̀nà láti fi ìmọ̀ kún ìmọ̀. Oníṣègùn kan tí í ṣe ikọ̀ òṣìṣẹ́ ìlera tí ó ṣe ìrìnàjò náà sọ wípé:

The protagonist of the case is very similar to the patients we often encounter in the accident and emergency wards – drug addicts, street sleepers, refugees. We all have to rescue them in the emergency room. But usually they are quite hostile in their attitudes. It’s very difficult to deal with them and we tend to lose patience over time.

This guided tours remind us that we must be patient and should not become indifferent. And their lives are very miserable and they struggle hard to survive.

Ẹni ọ̀ràn yìí dà bíi àwọn aláàárẹ̀ tí a máa ń bá pàdé nínú ìyára ìtọ́jú àwọn tí ó ní ìjàmbá àti ìtọ́júu pàjàwìrì – àwọn tí egbògi olóró tí sọ di ìdàkudà, àwọn tí ó ń sun títì, àwọn ogún-lé-mi-dé. Iṣẹ́ẹ gbogbo wa ni láti dóòlà ẹ̀míi wọn ní yàráa pàjàwìrì. Àmọ́ wọ́n máa ń kanra nígbà mìíràn. Kì í rọrùn bí a bá ń ṣe ìtọ́júu wọn, nítorí náà a máa sọ sùúrù nù.

Ìrìnàjò afẹ́ yìí rán wa létí wípé a nílòo sùúrù bí a bá ń dá àwọn aláàárẹ̀ lóhùn. Àti pé ayé ìrora ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ń tiraka láti gbé.

Onírúurú ikú ni yóò pa gbogbo àwọn olùgbée 20,000 Yau Ma Tei. Ìgbàgbọ́ọ wa ni wípé bí ikú bá kanlẹ̀kùn, ẹ̀míi wọn yóò máa ráre kiri ní àárín-in àdúgbò àti ní òpópónà, láti máa rán àwọn ènìyàn létí nípa ìtúmọ̀ ìwà láyé. Ìrìnàjò yìí ń lépa láti pèsè àyè fún àwọn òjìjí láti sọ ìtàn ara wọn.

Ohun tí ó ń fa ikú ni ìbàjẹ́ ọkàn tí a ò wò sàn. Ìbàjẹ́ ọkàn ní ìwòsàn, a sì lè dènà ìpànìyàn. Ó lè rí ìrànwọ́ fún àwọn tí ó ń bá ìparaẹni fà á àti àwọn tí ó wà nínú ìbàjẹ́ ọkàn. Lọ sí Befrienders.org fún ojú òpó ìbánisọ̀rọ̀ ìdènà ìparaẹni ní orílẹ̀-èdèe rẹ.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.