- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Pẹ̀lú àìbalẹ̀-ọkàn tí ó ń pọ̀ sí i ní ìmúra ìbò ààrẹ ọdún-un 2019, Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń bẹ̀rùu pípa ẹ̀rọ-ayélujára

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Nàìjíríà, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìbò, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣèlú, Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, Ìgbàwí GV

Ìbẹ̀rùbojo gba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan látàrí awuyewuye pé ó ṣe é ṣe kí ẹ̀rọ ayélukára-bí-ajere ó di pípa ní àsìkò ìbò ààrẹ ọdún-un 2019. TÀN / PA ẹ̀rọ agbénisókè-sílẹ̀. Àwòrán láti ọwọ́ọ Andrew Huff. [Creative Commons (CC BY-NC 2.0)/ Flickr, ọjọ́ 20, oṣù Ṣẹrẹ ọdún-un 2007]

Ẹ̀rù ti ń tàn ká orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wípé ó ṣe é ṣe kí ìjọba ó pa [1] ẹ̀rọ-ayélujára ní àsìkò ìbò ààrẹ nínú oṣù Èrèlé ọdún-un 2019. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ bí àhesọ lásán ti ń di ohun tí ó ń gbé àwọn ènìyàn ní ọkàn bí ìbò ṣe ń sún mọ́lé. Yomi Kamez ti Quartz Africa ṣàlàyé [2]:

You can tell fears of an internet shutdown are running high in a country when citizens are looking into methods of staying online in case of a blockage. This past weekend, Quartz Africa’s guide to staying online [3] during internet or social media blockages was our most read story, driven entirely by traffic from Nigeria. Scores of people shared concerns on social media at the possibility Nigeria might follow other African countries [like Sudan, Zimbabwe] that have taken to blocking social media or shut down the internet altogether under the guise of security concerns.

A lè sọ wípé ìbẹ̀rùbojo nípa pípa ẹ̀rọ-ayélujára ń gbilẹ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè tí àwọn ọmọ-ìlú ń wá ìlànà tí yóò mú wọn wà ní orí ayélukára-bí-ajere bí ìdígàgá bá wáyé. Ní ìsinmi tí ó kọjá lọ, ìtọ́sọ́nà bí a ṣe lè wà ní orí ayélukára-bí-ajere [3] ti Quartz Africa kó jọ bí ìdígàgá ẹ̀rọ-ayélujára tàbí ẹ̀rọ-alátagbà bá wáyé ni ìròyìn-in wá tí àwọn òǹkàròyìn kà jù lọ, tí ọ̀pọ̀ sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó sọ ní orí ẹ̀rọ-alátagbà wípé a kì í ṣe é mọ̀, Nàìjíríà lè tọ ipa ẹsẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ [bíi Sudan, Zimbabwe] tí ìjọba ti dígàgá ẹ̀rọ-alátagbà tàbí pa ẹ̀rọ-ayélujára ní àpapọ̀ ní ìrí ọ̀ràn ààbò.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó jẹ́ mọ́n ẹ̀rọ-alátagbà, ọ̀rọ̀ ìkórìíra, ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ àti ìrọ́pòw adájọ́, àti àìgbàgbọ́ nínú ilé iṣẹ́ ìròyìn ni ó parapọ̀.

Yíyọ-eyín onídàájọ́ àti ìdọ́gba lábẹ́ òfin

Ní ọjọ́ 25, oṣù Ṣẹrẹ ọdún-un 2019, ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí Ààrẹ Muhammad Buhari ní òun nìkan dá Adájọ́ Àgbà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Onídàájọ́ Walter Onnoghen dúró ní ẹnu iṣẹ́, tí ó sì yan ẹlòmíràn ní kíákíá, ìyẹn Ibrahim Tanko Muhammad ẹni tí a búra fún gẹ́gẹ́ bíi aṣiṣẹ́ bíi Adájọ́ Àgbà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (CJN).

Ẹ̀sùn àìbìkítà àti ìṣowó-ìlú-mọ́kumọ̀ku ni a fi kan Onnoghen. Síbẹ̀, àwọn alátakò sọ wípé ẹ̀sùn wọ̀nyí jẹ́ ìgbésẹ̀ láti di àjọ onídàájọ́ ní ẹnu [4] ní ìpalẹ̀mọ́ ìbò, àti dáyàfo ẹ̀ka ìjọba tí ó kù.

Ìdádúróo Onnoghen ta ìpá sí òfin Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ọdún-un 1999 [5] fún ìyọkúrò àwọn adájọ́.  Àlàálẹ̀ Ìkẹta, Apá 1, ti ìwé òfin ọdún-un 1999 sọ wípé Àjọ Onídàájọ́ (NJC) nìkan ni ó ní àṣẹ láti lè rọ adájọ́ ní oyè. Apá IV ìwé òfin náà túbọ̀ sọ síwájú nípa òfin yìí.

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari kò tẹ̀lé àwọn àlàálẹ̀ wọ̀nyí. Ó fi ipá gba agbára lọ́wọ́ NJC tí ó ní àṣẹ ní abẹ́ òfin láti sọ bóyá kí a rọ adájọ́ tàbí aṣojú-ṣòfin (ilé ìgbìmọ̀ àgbà) ní oyè, tí yóò sì fi ohùn sí irúfẹ́ ìgbésẹ̀ náà. Ìwà ìfagbáraṣèjọba ni ààrẹ hù, bẹ́ẹ̀ ni kò sì bá òfin mú.

Ìrò olóòtú ìwé ìròyìn Punch [6] pe ìhùwàsíi Buhari gẹ́gẹ́ bíi ti apàṣẹ-wàá àti pé ìwà náà lè fa rògbòdìyàn-an ti òfin:

Buhari’s action is vile, perfidious and indefensible. It is an action only fit for jackboot regimes, where the constitution could easily be suspended … Needless to say, the president’s singular and misguided action has the tendency to plunge the country into an unnecessary constitutional crisis and, perhaps, derail 20 unbroken years of democratic governance. This is not unlike other despotic and undemocratic acts that the government has been associated with  in the past, even if it might be considered more audacious, far-reaching and probably unexpected.

Ìhùwàsíi Buhari burú jáyì, ó ní ẹ̀tàn nínú, kò sì ní orí kò sì ní ìdí. Ìwà àkóso ìjọba fàmílétèntutọ́, tí ìwé òfin lè di ìfọwọ́rọ́tìsẹ́gbẹ̀ẹ́… Ní ti òtítọ́, ìwà àdánìkanṣe ààrẹ lè da ìwé òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà rú yányán, bóyá, ó lè da ìrìnàjò ogún ọdún ìjọba tiwantiwa rú. Èyí kò yàtọ̀ sí àwọn ìwà ìfagbáraṣèjọba àti ìtàpá sí ìjọba àwa-arawa tí a ti mọ ìṣàkóso ìjọba náà mọ́n, kódà bí a bá kà á sí ìwàa kò kàn mí, tí ó nípa tí ó pọ̀ àti tí a kò lérò.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà [7]àti United Kingdom [8] náà sọ̀rọ̀ òdì sí ìdìgbòlùu àjọ onídàájọ́. Ní oríi gbàgede ẹ̀rọ-alátagbà Twitter, àwọn ènìà ń sọ.

Iṣẹ́-ìjẹ́ sí @MBuhari [9] kò lè #EndTyranny [10] kí o sì fi ọwọ́ fún òfin àti ìdọ́gba ní abẹ́ òfin. Dá ìdádúró Onnoghen padà #OnnoghenSuspension [11] pic.twitter.com/BCPMzarZ6L [12]

– #FreeFejiAdeyanju (@wildeyeq)

Ọjọ́ 27, oṣù Ṣẹẹrẹ ọdún-un 2019

“Bí ààrẹ bá fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí atasẹ-àgẹ̀rẹ̀ s'òfin, ó ń sọ fún gbogbo ènìyàn láti atasẹ-àgẹ̀rẹ̀ s'òfin”

Ìgbógunti ọ̀rọ̀ ìkórìíra ni gbólóhùn tuntun ‘ààbò orílẹ̀-èdè’ 

Àmì mìíràn tí ó ń tọ́ka sí wípé ó lè bọ́ sí kí wọn ó ti ayélujára pa ni èròńgbà ìjọba láti pa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ orí ayélujára mọ́n ní ìbámu pẹ̀lú dídáàbobo orílẹ̀-èdè . Ní kò pẹ́ kò pẹ́, ìjọba pa àṣẹ fún àwọn agbófinró láti “wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣ'àdá lórí ọ̀rọ̀ ìkórìíra, pàápàá ní orí ẹ̀rọ-alátagbà.” Èyí, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn láti ọwọ́ọ Cable ti ṣe sọ,  [18]yóò jẹ́ mímú ṣẹ nípasẹ̀ ṣíṣe alamí aṣàmúlò ẹ̀rọ-alátagbà “ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó lókìkí.”

Nínúu oṣù Agẹmọ ọdún-un tí ó kọ́ja, Olórí Ẹ̀ka tí ó ń rí sí Ètò Gbígbé Ọ̀rọ̀ Síta fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Láí Mohammed ní wípé ewu ńlá ni  ìbísí àhesọ ìròyìn àti ọ̀rọ̀ ìkórìíra tí ó ń gbilẹ̀ yóò mú bá ààbò orílẹ̀-èdè [19]. Ní ọdún méjì sẹ́yìn, Nasir El-Rufai [20], gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, sọ wípé àhesọ àti ọ̀rọ̀ ìkórìíra jẹ́ “ìṣòro ńlá” tí ó lè fa ìfọ̀kànbalẹ̀, ààbò ẹ̀mí àti dúkìá orílẹ̀-èdè yà.

Bí ó ti wù kí ó rí, pẹ̀lú ẹ̀gàn ni ó jẹ́ pé ọ̀ràn-an àhesọ àti ọ̀rọ̀ ìkórìíra kan Lai àti El-Rufai gẹ́gẹ́ bíi ìṣòro ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bí olóṣèlú ẹgbẹ́ alátakò, àwọn méjèèjì kò ní ẹ̀rí tí ó dájú tí yóò fi ìdí ẹ̀sùn tí ó fi kan ìjọba àná múlẹ̀.

Fún àpẹẹrẹ, Nassir El-Rufai, gómìnà ìpínlẹ̀ẹ Kaduna lọ́wọ́lọ́wọ́ tẹnu mọ́ ọn ní ọdún-un 2014 — láìsí ẹ̀rí — wípé “ẹni kéje ni òun jẹ́ nínú àwọn tí [Ààrẹ Jónátàànì Goodluck] fẹ́ ṣe ikú pa [21]”.

Torí èyí, mo fẹ́ lọ sí orí ibùsùn. Èmi ni ẹni 7 tí GEJ fẹ́ ṣe ikú pa, nítorí náà mi kò ní da araà mi ní ààmú àyàfi bí GMB, Aṣíwájú, Amaechi, Àkàndé, àti àwọn tí ó kù bá kú!

El-Rufai tún sọ wípé nígbà tí Goodluck ń tu ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, jẹ́ agbátẹrù ẹgbẹ́ apani-ní- ìfọnná-finṣu Boko Haram. Bẹ́ẹ̀ náà ni Láí Mohammed tí ó ti ṣe Akọ̀wé Alukoro Orílẹ̀-èdè  rí fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ṣe sọ [23].

Gẹ́gẹ́ bíi olóṣèlú alátakò [24], àwọn òṣìṣẹ́ ọba ti fi hàn wípé àwọn gan-an ni adárúgúdù tí ó ń dá àhesọ àti ọ̀rọ̀ ìkórìíra sílẹ̀ [25], tí ó ń lo ẹ̀rọ-alátagbà fi dá rúgúdù sílẹ̀. Àmọ́ wọn kò rí ìwàa wọn gẹ́gẹ́ bíi ewu fún ààbò àti àlàáfíà orílẹ̀-èdè; wọn kò di ẹni à ń fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú tàbí mú kí a pa ayélujára nítorí ìwàa wọn.

Ẹ̀rọ-alátagbà àti ìbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ìjà fún ìyàtọ̀ ìgbé-ayé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ọdún-un 2012 #OccupyNigeria [26] àti ìpolongo  ọdún-un 2014 #BringBackOurGirls [27] mi gbogbo àgbáyé tìtì nítorí wípé àwọn ènìyàn ṣe àmúlò ẹ̀rọ-alátagbà fún ìpolongo ẹ̀dùn ọkàn-an wọn.

Ní ọdún-un 2015, ẹ̀rọ-alátagbà kó ipa ribiribi [28] nínú ìbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí Twitter di ibi ìkorò àti gbàgede ìjà ìpínyà ní àsìkò ìpolongo, a sì mú u lò fún ìtànká ọ̀rọ̀ ìkórìíra àti ìròyìn tí kò ní òtítọ́ kan nínú.

Ní ọdún tí a wà yìí, ó ti ṣe ojúṣe gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà kan tí àwọn ọ̀dọ́ọ Nàìjíríà yàn láti ní ẹnu nínú ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Àwọn tí ó ń lo ẹ̀rọ-ayárabíaṣá ti ṣe àmúlò ẹ̀rọ-alátagbà láti fi pe ìjọba sí àkíyèsí, bíi ti ìdádúró-lẹ́nu-iṣẹ́ ti CJN, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò bá ti máà jẹ́ mímọ̀ fún ọmọ ìlú.

Àwọn ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi orí ẹ̀rọ-alátagbà sọ ohun tí ó ń gbé wọn ní ọkàn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n lò ó fi yọ ìjọba lẹ́nu láti pa èròńgbàa rẹ̀ tì àti fún ìfẹ̀hónúhàn:

Bó yá ayélujára wà ní àsìkò ìbò tàbí kò ní í wà, ìdí tí ó dájú ń bẹ láti ní ìgbàgbọ́ wípé ọ̀rọ̀ òṣèlú ní orí ayélukára-bí-ajere àti ní ojú òpópónà yóò jẹ́ ohun tí ìjọba yóò fi ojú sí.