- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Òwìwí kan kọ̀ kò kúrò nínú ilé ìgbìmọ̀ ìjọba Tanzania. Àmìi kí ni èyí?

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Tanzania, Ètò ìjọba, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣèlú, Iyè-inú

Gbàgede Nyerere Square ní Dodoma, olú-ìlú orílẹ̀-èdè Tanzania, àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ”Bunge.” Àwòrán láti ọwọ́ọ Pernille Bærendtsen, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Ní ọjọ́ 29 oṣù Ṣẹrẹ, nígbà tí àwọn àjọ ìjọba Tanzania (Bunge) péjọ ní Dodoma fún ìjókòó ìpàdé tí ó ṣáájú nínú ọdún-un 2019, ẹyẹ òwìwí kan fò wọ inú ilé ìpàdé, ó sì bà sí orí ajá, níbi tí ó ti ń wo ìpéjọ láti òkè téńté.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà di ìròyìn tí ó sì tàn kálékáko, tí ó sì ń mú àwọn ènìyàn ṣe onírúurú ìbéèrè láti orí ẹ̀rọ-alátagbà àti ìwé ìròyìn. Àpẹẹrẹ wo ni ti òwìwí nínú ilé ìgbìmọ̀? 

Ẹyẹ òwìwí náà ti jẹ́ rírí nínúu gbọ̀ngan ilé ìgbìmọ̀ ìlú Dodoma ní ẹ̀rìnmejì. Àpẹẹrẹ wo ni èyí túmọ̀ sí?

‘’Àmì burúkú? [3]’’ ìwé ìròyìn ẹkùn-ìlú ọlọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀, Ìlà-oòrùn Afrika, dá ìmọ̀ràn.

Akọbúlọ́ọ̀gù ọmọ Gẹ̀ẹ́sì àti onímọ̀ kíkún nípa iṣẹ́ ìròyìn, Ben Taylor, sọ síwájú sí i:

Àwòrán-ẹ̀fẹ̀ láti ọwọ́ọ Samuel Mwamkinga (Joune), a lòó pẹ̀lú àṣẹ.

Ayàwòrán-ẹ̀fẹ̀ ọmọ bíbíi Tanzania, Samuel Mwamkinga (Joune) [5], lẹ́yìn wá, ya àpẹẹrẹ àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà pẹ̀lú ìtọ́ka sí ìsọlọ́rúkọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ‘’àkójọpọ̀ àwọn òwìwí’’ látàrí ìmọ̀ àwọn Gíríìkì tí ó ní wípé ọlọ́gbọ́n ni ẹyẹ òwìwí (pẹ̀lú àṣẹ ni a fi lo àwòrán àpẹẹrẹ).

Síbẹ̀, ojú nǹkan búburú, àmì ikú àti òfo [6] ní Tanzania ni àwọn ènìyàn fi wò ó.

Àti pé — òwìwí náà ti pinnu láti dúró sí Bunge, gẹ́gẹ́ bí Ọmọọ̀lú Náà ti wí:

Òwìwí, ẹyẹ òru, kò le è kúrò … pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà tí àwọn àjọ ọba gbà láti lé e jáde.

Ẹyẹ òwìwí kì í ṣe ẹyẹ rere ní Tanzania, àti pé, bẹ́ẹ̀ ni Tanzania kì í ní ìgbàgbọ́-asán. Ìwò káàkiri ọdún-un 2010 [7] kan fi hàn wípé ìdá 94 ọmọ bíbí Tanzania ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Àjẹ́.

Ìpàdé ìgbìmọ̀ lásán kọ́ 

Fún ti ìpàdé yìí, ẹyẹ òwìwí nínúu ìpàdé ní ìtúmọ̀ tí ó ní àpẹẹrẹ, pàápàá fún àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́-asán, tí ó le pátápátá láti mú ojú kúrò. 

Ní orí ìlànà ètò ìpàdé àkọ́kọ́ ìgbìmọ̀ọ Tanzania ọdún-un 2019 ni ìdámọ̀ràn àtúnṣe sí Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú, tí ó ti ní àríyànjiyàn lemọ́lemọ́ nínúu ìṣèlú tí nǹkan kò ṣe ẹnu re. 

Tanzania wọ ìwé ìtàn [8]ní ọdún-un 1992 gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ní Ilẹ̀-adúláwò tí yóò dá ètò ẹgbẹ́ òṣèlú púpọ̀ sílẹ̀, èyí tí ó fi àyè gba ẹgbẹ́ ìkọjúsí. Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú náà (rè é níbi pẹ̀lú àtúnṣe tí a gbà ní ìmọ̀ràn)  [9] bákan náà di lílò ní ọdún-un 1992, ó sì ti rí àtúnṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà bíi àtúnṣe ti ọdún-un 2009. 

Pẹ̀lú wípé òwìwí wọ̀ sí òkè téńté nínúu ìpàdé, kò dí ìpinnu àwọn ìgbìmọ̀ lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe sí òfin — ìgbésẹ̀ tí àwọn atàbùkù ní wípé ó sọ ètò ẹgbẹ́ òṣèlú púpọ̀ Tanzania, àti ìjọba tiwantiwa bákan náà di yẹpẹrẹa step that critics regard as a serious weakening of the multiparty system in Tanzania, and thus also democracy.

Gẹ́gẹ́ bí Reuters [10] ti ṣe wí, ìsọdituntun òfin náà ti fi agbára tí ó pọ̀ sí ọwọ́ àwọn akọ̀wé ìrántí tí ìjọba-yàn láti da ìwé àṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú nù àti láti fi ìyà ìfisẹ́wọ̀n jẹ ẹgbẹ́ olóṣèlú tí ó bá ṣẹ̀ sí òfin, ní àpẹẹrẹ, bí ó bá ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìlú tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìforúkọsílẹ̀ òǹdìbò àti àgbékalẹ̀ ètò mìíràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣèlú.

Ọ̀pọ̀ ilé-ìròyìn ni ó ṣe àtúnwí ọ̀rọ̀ Zitto Kabwe, olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ACT-Wazalendo, ẹni tí ó jẹ́ wípé nínú oṣù Ògún ọdún-un 2017 [11] bu ẹnu àtẹ́ lu ìdámọ̀ràn àtúnṣe òfin náà, wípé ó ṣe é ṣe kí ó rọ́ ẹ̀tọ́ òṣèlú sẹ́yìn. Kabwe wá fi wé Àbádòfin Iṣẹ́ Ìròyìn ọdún-un 2016, èyí tí ó fi òmìnira fún ilé iṣẹ́ ìròyìn tí ó sì dá ilé ìròyìn aládàánialáìgbáralé-ìjọba padà.  [12]Wàyí, Kabwe pe àkíyèsí sí ìjì lẹ́sẹ̀ tí àtúnṣe Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú dá sílẹ̀: 

A kò le è ní ìwé-òfin tí ó fi ẹ̀tọ́ fún òmíràn ìkẹ́gbẹ́ kí ó tún wá fún ẹnìkan ní agbára láti mú ẹ̀tọ́ òmìnira ìkẹ́gbẹ́ kúrò.

Ìjọba àwa-arawa tí ó ń kú lọ?

Ìjọba tiwantiwa tí ó ń fi ìdí rẹmi ní abẹ́ ìṣàkóso Ààrẹ Magufuli ti di fòníkú-fiọ̀ladìde nínú ìròyìn, ó sì ti di ọ̀rọ̀ àwàdà.

Ní ọjọ́ 30 oṣù Ṣẹrẹ, Fatma Karume, Alága Ẹgbẹ́ Òfin Tanganyika, túwíìtì àwòrán-ẹ̀fẹ̀ kan láti ọwọ́ọ ayàwòrán-ẹ̀fẹ̀ ọmọ bíbíi Kenya, Gado (Ọjọ́ 22, oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún-un 2017) tí ó ń tọ́ka sí ọwọ́ Ààrẹ orílẹ̀-èdè Tanzania Magufuli nínú ikúu ìjọba àwa-arawa: 

Ní ẹnu ọdún mélòó kan sẹ́yìn, òfin orílẹ̀-èdè Tanzania ti ń yí padà di aláfagbára ṣe [15], arapa rẹ̀ sì ń fa àìrí àyè fún ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn àti ilé iṣẹ́ ìròyìn aláìgbáralé-ìjọba láti ṣe bí ó ṣe ní abẹ́ òfin. Ní báyìí, àwọn aṣàyẹ̀wò fínnífínní ti sọ wípé àtúnṣe Òfin Ẹgbẹ́ Òṣèlú kò ní mú un rọrùn fún ètò ìṣèlú tí ó jẹ́ pàtàkì fún Ààrẹ àti Chama Cha Mapinduzi (Ẹgbẹ́ Àyípadà Náà), tí ó ti wà ní orí àlééfà láti ìgbà tí òmìnira dé ní ọdún-un 1961.

Ìtakò jẹ́ dandanàndan nínú ìjọba tiwantiwa tí ó yé kooro. Alátakò gidi yóò ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí ètò ìjọba, yóò sì pè é ní ìjà. Bí kò bá sí alátakò, ó ṣe é ṣe kí ojú àwọn onírúurú ìyàtọ̀ ohun tí ọmọ-ìlú nílò ó máa jẹ́ ṣíṣe bí ó ti ṣe tọ́. 

Nínú túwíìtì 15 [16], akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn Rachel McLellan la àwọn ènìyàn ní òye nípa èrèdíi òfin tuntun náà, àti irú ibi tí ìtako tí ó mú ọpọlọ dání yóò ti wúlò :walked readers through possible consequences of the new act, and characterizes a situation where a critical opposition will find itself cornered: 

Ìgbàgbọ́-asán ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ – àwọn tí ó ń ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣèjọba àfagbáraṣe orílẹ̀-èdè Tanzania rí ìdánilójú awuyewuye wọn pẹ̀lú ti ẹyẹ òwìwí tí ó wọ inú ilé ìgbìmọ̀ àti ìgbésẹ̀ gbogbo láti lé e dánú àmọ́ tí kò bọ́ sí i.

Òwìwí náà ta kété. Agbẹnusọ Ìgbìmọ̀, Job Ndugai, gbìyànjú láti yí ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀ padà pẹ̀lú àlàyé tí ó ní iyè nínú: 

Ẹ̀yin Ọmọ Ìgbìmọ̀ Ọlọ́lá, a ti ń rí ẹyẹ òwìwí kan nínú Ilé yìí láti òwúrọ̀ àmọ́ nínú ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀ Dodoma, òwìwí tí a bá rí ní ojú-ọjọ́ kò ní ohunkóhun ń ṣe fún ẹnikẹ́ni [3]. Èyí jásí wípé kò sí ìbẹ̀rù.

Fún àwọn tí ó ń wá àṣìṣe, síbẹ̀, kò sí ohun tí ó ní iyè nínú nípa òfin tuntun náà.