- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wọ̀yáàjà láti nípa lórí ètò ìdìbò ọdún-un 2019

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Nàìjíríà, Ètò ìjọba, Ìbò, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣèlú

Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, Ààrẹ àná orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [Creative Commons (CC BY 2.0)/ Flickr, Oṣù Òkúdù, Ọdún 2011.]

Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ń múra fún ètò ìdìbò sí ipò Ààrẹ nínú Oṣù Èrèlé, àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí wọn di olóṣèlú, jẹ́ igi gbòógì fún òye ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tàbí àwọn tí wọn ṣe àtìlẹ́yìn fún láti dé orí ipò ni ó ti ń tukọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1999 tí ìjọba tiwantiwa ti padà.

Asọ̀ tí ó wáyé láìpẹ́ yìí láàárín Ààrẹ àná, Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ [1] àti Ààrẹ tí ó wà lórí àlééfà, Ààrẹ Muhammadu Buhari – tí àwọn méjèèjì jẹ́ ajagun fẹ̀yìntì afipásèjọba ológun –ní ipa tí ó pọ̀ lórí ètò ìdìbò oṣù tí ó ń bọ̀.

Nínú ìwé àpilẹ̀kọ kan tí a kò rí irúu rẹ̀ rí tí ó kọ ránṣẹ́ sí Buhari [2], Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kàn-án wípé ó ní ètè láti ṣe èrú ìbò. Ó kọ ọ́ sínú ìwé náà wípé:

Ìtìjú ńlá gbáà ló jẹ́ fún ìjọba tiwantiwa, bí ètò ìbò tí o yẹ kí ó lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀ láì fi ti apá kan ṣe, ṣùgbọ́n tí ìṣesíi wọn kò fi ìṣedéédé hàn, àìmúdọ́gba tí ó hàn kedere, ẹ̀tàn àti ìjòye àwòdì máà le è gbẹ́dìẹ.

Ọbásanjọ́ tẹnu mọ́ ọn wípé Buhari kò leè “ṣe ètò ìbò tí ó kẹ́sẹjárí”, àti wípé ìsèjọba tiwantiwa ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari ni a lè fi wé tí ìjọba ológun fàmílétè-kí-n-tutọ́ọ ti Abacha.

Ní ọdún 1998, Sani Abacha [3], tí ó jẹ́ ológun apàṣẹwàá ní ìgbà náà, pè fún ìbò gbogboògbò ṣùgbọ́n tí ó hàn ketekete pé Abacha kò ṣetán láti gbé ìjọba sílẹ̀ fún alágbádá. Ní àsìkò tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó fọwọ́ síi wípé kí Abacha ó jẹ́ olùdíje fún ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlúu wọn. Ní báyìí ó ti ṣípò-padà, òkìkí Abacha tàn káàkiri ó sì di ìlú-mọ̀-ọ́-ká nípa ìtẹrí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn mọ́lẹ̀ àti ìjẹgùdùjẹrà [4]. Ọbásanjọ́ tẹnumọ́ọ wípé “ipasẹ̀” Abacha ní ọjọ́ kínní àná náà ni Buhari ń tọ́ báyìí “láì wo ẹ̀yìn wò.”

Shehu Garba, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari lórí gbígbé ìròyìn jáde, bu ẹnu àtẹ́ lu [5] ìwé àpilẹ̀kọ Ọbásanjọ́:

Ètò ìdìbò tí yóò wáyé nínú osù tí ó ń bọ̀ yìí yóò lọ ní pẹ̀lẹ́-kùtù, gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Buhari ti ṣe ìlérí fún ọmọ orílẹ̀-èdè yìí àti àgbáyé.

Ọbásanjọ́, òǹkọ̀wé àpilẹ̀kọ? 

Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, tí ó jẹ́ Ààrẹ ìjọba ológun àná (láti ọdún 1976 sí 1979), tí ó sì tún ṣe  Ààrẹ ìjọba alágbádá tí ìbò gbé wọlé (ní ọdún 1999 sí 2007), kúndùn láti máa bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ètò ìjọba Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ tẹ̀lé e.

Ní èṣí, Ọbásanjọ́ gba Buhari ni ìmọ̀ràn láti má díje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, ṣùgbọ́n kí ó “da ìfẹ̀yìntì rò [6] nítorí ọjọ́ oríi rẹ̀.” Àmọ̀ràn yìí dá yánpọnyánrin sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí wípé Ọbásanjọ́ jẹ́ alátìlẹ́yìn àgbà [7] fún Buhari gẹ́gẹ́ bí òǹdíje nínú ìbò ipò Ààrẹ ni sáà àkọ́kọ́ ní ọdún 2015.

Ṣáájú àsìkò yìí, Ọbásanjọ́ ti bá ìjọba Goodluck Jónátánì [8] wí nínú ìwé àpilẹ̀kọ tí ó kọ ránṣẹ́ sí i ní ọdún 2013, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kan Jónátánì [9] wípé ó ń darí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí oko ìparun pẹ̀lú bí ó ṣe fi àyè gba ẹ̀tàn, ìjẹ́gùdùjẹrà, ìbápín àìgbẹ́kẹ̀lé láti fa aṣọ iyì àti ìtẹ̀síwájú orílè-èdè náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”

Ní àpárá, Ọbásanjọ́ ti Goodluck Jónátánì lẹ́yìn nínú ètò ìdìbò tí ó wáyé ní ọdún 2011. Àti wípé ni ọdún 2007, òun yìí kan náà ni ó ti Umaru Musa Yar'Adua [10] tí ó jẹ kí Jónátánì ó tó jẹ lẹ́yìn digbídigbí. Ṣùgbọ́n tí ó pa ìdí ọ̀rẹ́ dá sí Yar'Adua lẹ́yìn ìgbátí ó bẹ̀rẹ̀ àìsàn tí kò sì gbé ètò ìṣe ìjọba fún igbákèjì rẹ̀ tii ṣe Goodluck Jónátánì.

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àná Goodluck Jonathan with pẹ̀lú Ààrẹ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí àlééfà Muhammadu Buhari níbi ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ ìjọba tuntun ní ọjọ́ 29, oṣù Èbìbì, ọdún 2015. Àworan Ìkápá Gbogboògbòw láti ẹ̀ka ìjọba US.

Ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì kì í sinmi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Abẹ ìgbèkùn àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì àti àwọn asọ́mogbée wọn ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà. Bí àpẹẹrẹ, Ọbásanjọ́ jẹ́ alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó mọ àludé tòun àpadé bí àwọn Ààrẹ ṣe ń gba ipò láti ọdún 2007 sí 2015. Bíótiwùkíórí, láì jọ ti àwọn alágbádá – Yar'Adua àti Jónátánì – tí ó gbé ní arugẹ, tí ó sì tún yẹpẹrẹ wọn, ti Buhari dá yàtọ̀ gedegbe.

Bí ó ti lẹ̀ jé pé Ọbásanjọ́ ti Buhari lẹ́yìn láti leè yege ní ọdún 2015, a kò leè sọ pé àtìlẹyìn rẹ̀ nìkan ni ó gbé e dé ipò Ààrẹ. Nítorí ohun tí ó jẹ́ kí ó ṣeé ṣe ò ju bí Buhari ṣe fi ọwọ́ wẹ ọwọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú ìgbàanì Action Congress of Nigeria (ACN) ti Bọ́lá Tinubu [11]. Ẹgbẹ́ òṣèlú Congress for Progressive Change (CPC) ti Buhari jẹ ọmọ ẹgbẹ́ ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín parapọ̀ mọ́ ACN, wọ́n sì di ọkàn nínú oṣù Kejì ọdún 2013, èyí tí ó ṣe okùnfà ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú Gbogboògbò [12] (APC).

Ní àfikún, Buhari tí ó ṣe olórí ìjọba ológun ní ọdún (1983 sí 1985) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ‘ẹgbẹ́’ ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tí ó ti takú ti ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Fún ìdí èyí, bí Ọbásanjọ́ ṣe tàbùkù Buhari ní gbangba tó, ó níí ṣe pẹ̀lú agbára àti ipò ẹgbẹ́ tí àwọn méjèèjì wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì.

Ọbásanjọ́ nìkan sì kọ́ ni ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí ó ń tàbùkù Buhari.

Theophilus Danjuma [13], tí òun náà jẹ́ ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì ní oṣù kẹ́ta ọdún tí ó kọjá fi ẹ̀sùn kan [14] “ẹgbẹ́ ológun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wípé ó ń gbárùkù ti ìpànìyàn nípakúpa tí ó ń lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”

Danjuma, tí ó jẹ olórí àwọn ológun, tí o si tún jẹ́ mínísítà fún ètò abo ní ìgbà kan rí, bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ́ ológun bí wọ́n ṣe ń gbé lẹ́yìn apá kan dá apá kan sí nínú aáwọ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn darandaran àti àgbẹ̀ [15], pàápàá jù lọ èyí tí ó wáyé ní ilée rẹ̀ tí í ṣe ìpínlẹ̀ Taraba. Ìrí-bá-kan-náà, Danjuma fi ariwo ta nípa ète bí àwọn “ọlọ́pàá àti ológun” ṣe ń gbìmọ̀pọ̀ láti ṣe ẹ̀rú [16] nínú ìbò ọdún 2019.

Bákannáà ẹ̀wẹ̀wẹ̀, nínú Oṣù Kejì ọdún tí ó kọjá, ajagun fẹ̀yìntì tí ó tún jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láyé ológun, Ibrahim Babangida [17] gba Ààrẹ Buhari ní ìyànjú láti máà du ìje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, nítorí wípé ọgọ́rùn-ún ọdún 21 tí Nàìjíríà wà yìí jẹ́ àsìkò àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ìrírí ìgbàlódé. Ó gbàgbọ́ wípé ìgbàkanìgbàkàn “ohun tí yóò jẹ́ àǹfààní gbogbo ará ìlú gbọdọ̀ bo orí àǹfààní ti ara ẹni.”

Pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ, yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ pẹ́ díẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó tó le è ní Ààrẹ tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú, tàbí tí kò ní àtìlẹ́yìn ‘ẹgbẹ́’ àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì.