Àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wọ̀yáàjà láti nípa lórí ètò ìdìbò ọdún-un 2019

Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, Ààrẹ àná orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [Creative Commons (CC BY 2.0)/ Flickr, Oṣù Òkúdù, Ọdún 2011.]

Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ń múra fún ètò ìdìbò sí ipò Ààrẹ nínú Oṣù Èrèlé, àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí wọn di olóṣèlú, jẹ́ igi gbòógì fún òye ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tàbí àwọn tí wọn ṣe àtìlẹ́yìn fún láti dé orí ipò ni ó ti ń tukọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1999 tí ìjọba tiwantiwa ti padà.

Asọ̀ tí ó wáyé láìpẹ́ yìí láàárín Ààrẹ àná, Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ àti Ààrẹ tí ó wà lórí àlééfà, Ààrẹ Muhammadu Buhari – tí àwọn méjèèjì jẹ́ ajagun fẹ̀yìntì afipásèjọba ológun –ní ipa tí ó pọ̀ lórí ètò ìdìbò oṣù tí ó ń bọ̀.

Nínú ìwé àpilẹ̀kọ kan tí a kò rí irúu rẹ̀ rí tí ó kọ ránṣẹ́ sí Buhari, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kàn-án wípé ó ní ètè láti ṣe èrú ìbò. Ó kọ ọ́ sínú ìwé náà wípé:

Ìtìjú ńlá gbáà ló jẹ́ fún ìjọba tiwantiwa, bí ètò ìbò tí o yẹ kí ó lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀ láì fi ti apá kan ṣe, ṣùgbọ́n tí ìṣesíi wọn kò fi ìṣedéédé hàn, àìmúdọ́gba tí ó hàn kedere, ẹ̀tàn àti ìjòye àwòdì máà le è gbẹ́dìẹ.

Ọbásanjọ́ tẹnu mọ́ ọn wípé Buhari kò leè “ṣe ètò ìbò tí ó kẹ́sẹjárí”, àti wípé ìsèjọba tiwantiwa ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari ni a lè fi wé tí ìjọba ológun fàmílétè-kí-n-tutọ́ọ ti Abacha.

Ní ọdún 1998, Sani Abacha, tí ó jẹ́ ológun apàṣẹwàá ní ìgbà náà, pè fún ìbò gbogboògbò ṣùgbọ́n tí ó hàn ketekete pé Abacha kò ṣetán láti gbé ìjọba sílẹ̀ fún alágbádá. Ní àsìkò tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó fọwọ́ síi wípé kí Abacha ó jẹ́ olùdíje fún ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlúu wọn. Ní báyìí ó ti ṣípò-padà, òkìkí Abacha tàn káàkiri ó sì di ìlú-mọ̀-ọ́-ká nípa ìtẹrí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn mọ́lẹ̀ àti ìjẹgùdùjẹrà. Ọbásanjọ́ tẹnumọ́ọ wípé “ipasẹ̀” Abacha ní ọjọ́ kínní àná náà ni Buhari ń tọ́ báyìí “láì wo ẹ̀yìn wò.”

Shehu Garba, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari lórí gbígbé ìròyìn jáde, bu ẹnu àtẹ́ lu ìwé àpilẹ̀kọ Ọbásanjọ́:

Ètò ìdìbò tí yóò wáyé nínú osù tí ó ń bọ̀ yìí yóò lọ ní pẹ̀lẹ́-kùtù, gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Buhari ti ṣe ìlérí fún ọmọ orílẹ̀-èdè yìí àti àgbáyé.

Ọbásanjọ́, òǹkọ̀wé àpilẹ̀kọ? 

Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, tí ó jẹ́ Ààrẹ ìjọba ológun àná (láti ọdún 1976 sí 1979), tí ó sì tún ṣe  Ààrẹ ìjọba alágbádá tí ìbò gbé wọlé (ní ọdún 1999 sí 2007), kúndùn láti máa bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ètò ìjọba Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ tẹ̀lé e.

Ní èṣí, Ọbásanjọ́ gba Buhari ni ìmọ̀ràn láti má díje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, ṣùgbọ́n kí ó “da ìfẹ̀yìntì rò nítorí ọjọ́ oríi rẹ̀.” Àmọ̀ràn yìí dá yánpọnyánrin sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí wípé Ọbásanjọ́ jẹ́ alátìlẹ́yìn àgbà fún Buhari gẹ́gẹ́ bí òǹdíje nínú ìbò ipò Ààrẹ ni sáà àkọ́kọ́ ní ọdún 2015.

Ṣáájú àsìkò yìí, Ọbásanjọ́ ti bá ìjọba Goodluck Jónátánì wí nínú ìwé àpilẹ̀kọ tí ó kọ ránṣẹ́ sí i ní ọdún 2013, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kan Jónátánì wípé ó ń darí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí oko ìparun pẹ̀lú bí ó ṣe fi àyè gba ẹ̀tàn, ìjẹ́gùdùjẹrà, ìbápín àìgbẹ́kẹ̀lé láti fa aṣọ iyì àti ìtẹ̀síwájú orílè-èdè náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”

Ní àpárá, Ọbásanjọ́ ti Goodluck Jónátánì lẹ́yìn nínú ètò ìdìbò tí ó wáyé ní ọdún 2011. Àti wípé ni ọdún 2007, òun yìí kan náà ni ó ti Umaru Musa Yar'Adua tí ó jẹ kí Jónátánì ó tó jẹ lẹ́yìn digbídigbí. Ṣùgbọ́n tí ó pa ìdí ọ̀rẹ́ dá sí Yar'Adua lẹ́yìn ìgbátí ó bẹ̀rẹ̀ àìsàn tí kò sì gbé ètò ìṣe ìjọba fún igbákèjì rẹ̀ tii ṣe Goodluck Jónátánì.

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àná Goodluck Jonathan with pẹ̀lú Ààrẹ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí àlééfà Muhammadu Buhari níbi ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ ìjọba tuntun ní ọjọ́ 29, oṣù Èbìbì, ọdún 2015. Àworan Ìkápá Gbogboògbòw láti ẹ̀ka ìjọba US.

Ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì kì í sinmi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Abẹ ìgbèkùn àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì àti àwọn asọ́mogbée wọn ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà. Bí àpẹẹrẹ, Ọbásanjọ́ jẹ́ alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó mọ àludé tòun àpadé bí àwọn Ààrẹ ṣe ń gba ipò láti ọdún 2007 sí 2015. Bíótiwùkíórí, láì jọ ti àwọn alágbádá – Yar'Adua àti Jónátánì – tí ó gbé ní arugẹ, tí ó sì tún yẹpẹrẹ wọn, ti Buhari dá yàtọ̀ gedegbe.

Bí ó ti lẹ̀ jé pé Ọbásanjọ́ ti Buhari lẹ́yìn láti leè yege ní ọdún 2015, a kò leè sọ pé àtìlẹyìn rẹ̀ nìkan ni ó gbé e dé ipò Ààrẹ. Nítorí ohun tí ó jẹ́ kí ó ṣeé ṣe ò ju bí Buhari ṣe fi ọwọ́ wẹ ọwọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú ìgbàanì Action Congress of Nigeria (ACN) ti Bọ́lá Tinubu. Ẹgbẹ́ òṣèlú Congress for Progressive Change (CPC) ti Buhari jẹ ọmọ ẹgbẹ́ ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín parapọ̀ mọ́ ACN, wọ́n sì di ọkàn nínú oṣù Kejì ọdún 2013, èyí tí ó ṣe okùnfà ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú Gbogboògbò (APC).

Ní àfikún, Buhari tí ó ṣe olórí ìjọba ológun ní ọdún (1983 sí 1985) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ‘ẹgbẹ́’ ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tí ó ti takú ti ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Fún ìdí èyí, bí Ọbásanjọ́ ṣe tàbùkù Buhari ní gbangba tó, ó níí ṣe pẹ̀lú agbára àti ipò ẹgbẹ́ tí àwọn méjèèjì wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì.

Ọbásanjọ́ nìkan sì kọ́ ni ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí ó ń tàbùkù Buhari.

Theophilus Danjuma, tí òun náà jẹ́ ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì ní oṣù kẹ́ta ọdún tí ó kọjá fi ẹ̀sùn kan “ẹgbẹ́ ológun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wípé ó ń gbárùkù ti ìpànìyàn nípakúpa tí ó ń lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”

Danjuma, tí ó jẹ olórí àwọn ológun, tí o si tún jẹ́ mínísítà fún ètò abo ní ìgbà kan rí, bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ́ ológun bí wọ́n ṣe ń gbé lẹ́yìn apá kan dá apá kan sí nínú aáwọ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn darandaran àti àgbẹ̀, pàápàá jù lọ èyí tí ó wáyé ní ilée rẹ̀ tí í ṣe ìpínlẹ̀ Taraba. Ìrí-bá-kan-náà, Danjuma fi ariwo ta nípa ète bí àwọn “ọlọ́pàá àti ológun” ṣe ń gbìmọ̀pọ̀ láti ṣe ẹ̀rú nínú ìbò ọdún 2019.

Bákannáà ẹ̀wẹ̀wẹ̀, nínú Oṣù Kejì ọdún tí ó kọjá, ajagun fẹ̀yìntì tí ó tún jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láyé ológun, Ibrahim Babangida gba Ààrẹ Buhari ní ìyànjú láti máà du ìje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, nítorí wípé ọgọ́rùn-ún ọdún 21 tí Nàìjíríà wà yìí jẹ́ àsìkò àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ìrírí ìgbàlódé. Ó gbàgbọ́ wípé ìgbàkanìgbàkàn “ohun tí yóò jẹ́ àǹfààní gbogbo ará ìlú gbọdọ̀ bo orí àǹfààní ti ara ẹni.”

Pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ, yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ pẹ́ díẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó tó le è ní Ààrẹ tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú, tàbí tí kò ní àtìlẹ́yìn ‘ẹgbẹ́’ àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.