Fún ìyọsọ́tọ̀ tí wọ́n yọ òun nìkan láti yẹ ara rẹ̀ wò ní ilé ìtajà ìgbàlódé kan ní Serbia, gbajúgbajà ìràwọ̀ òṣèré orí-ìtàgé Roma fi ẹ̀sùn ìwà elẹ́yàmẹyà kan ilé ìtajà náà

    Nataša Tasić Knežević, photo by Dzenet Koko, used with permission.Ìràwọ̀ òṣèré orí-ìtàgé ìlú Serbia Nataša Tasić Knežević, àwòrán láti ọwọ́ọ Dzenet Koko, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Àwọn gbàgede ìtàkùrọ̀sọ ẹ̀rọ-alátagbà ìlú Serbia gbaná lẹ́yìn tí olórin àti òṣèré ìbílẹ̀ Nataša Tasić Knežević, tí ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Roma fi ẹ̀sùn kan ilé ìtajà-ìgbàlóde kan tí ó wà ní ìgboro Novi Sad fún ìwà ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà nínú ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ojú-ẹsẹ̀ kan lórí Facebook.

Nínú fídíò náà, tí ó gbé-sórí-áfẹ́fẹ́ ní ọjọ́ 29, oṣù Ọ̀pẹ lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, arábìnrin Tasić Knežević ṣàlàyé pé bí òun ṣe ń jáde síta nínú ilé ìtajà ńlá náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn òǹrajà mìíràn ni ẹ̀rọ adènà àfọwọ́rá dún. Bí àwọn ènìyàn yòókù ṣe ń jáde síta, àwọn ẹ̀ṣọ́-aláàbò ilé ìtajà náà ní kí ó dúró tí wọ́n sì tẹ̀síwajú láti yẹ ara rẹ̀ wò ní gbangba tí àwọn òǹwòran bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́. Ìwé orin, ìwé àti àpò-àpawómọ́-ìléwọ́ ni wọ́n rí nínú àpò-àgbékọ́yìn-in rẹ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Ṣẹẹrẹ ọdún 2019, fídíò náà dédé pòórá pẹ̀lú àlàyé ránpẹ́ nípa arábìnrin Knežević. Bíótilẹ̀jẹ́pé kòì tíì wá sí gbangba kí ó ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé fúnra rẹ̀ ni ó yọ ọ́ kí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ lè tán bọ̀rọ̀. Láàárín ọjọ́ díẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó tó bíi ẹgbẹ̀rún 60 ti wo fídíò rẹ̀, tí wọ́n sì pín in lọ́nà 350, tí ó sì gba èsì tí ó tó 700.

Ilé iṣẹ́ Ìkóròyìnjọ Orí-ayélujára Olómìnira Bulka ni ó kọ́kọ́ ro ìyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣáájú àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn Bulka mìíràn.

Akọrin-olóhùn-òkè ni arábìnrin Tasić Knežević ní Gbọ̀ngan Eré-ìtàgé ti orílẹ̀-èdè Serbia tí ó wà ní Novi Sad, ìlú kejì tí ó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà. Tẹ́lẹ̀ rí, ó ṣiṣẹ́ ní Belgrade Atelje 212. Ó tún jẹ́ akọrin-ṣeré àti àdánìkànkọrin tí ó gbajúmọ̀, ó sì máa ń kọ orin àdánìkànkọ nípa àṣà Roma tí ó jẹ́ orírun rẹ̀.

Nínú fídíò náà, arábìnrin Knežević sọ pé alábòójútó ilé ìtajà náà bẹ̀bẹ̀ lẹ́yìn tí òun ṣe àròyé nípa ìwọ̀sí náà, ṣùgbọ́n pé inú òun kò dùn sí bí àwọn èrò tí ó pé jọ lé òun lórí ṣe yẹ̀yẹ́ òun. Ó ní ọkùnrin àgbàlagbà kan pariwo pé kí wọ́n “kó pàǹtí yẹn jáde”, ìyẹn túmọ̀ sí wípé kí àwọn òṣìṣẹ́ ó ju òun jáde síta nínú ilé ìtajà náà nítorí pé òun jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Rome.

“A mọ ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa jalè níbí” jẹ́ gbólóhùn kan láti inú eré “Ta ni ó ń kọrin níbẹ̀ yẹn!” nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ 5, oṣù Èbìbí ọdún 1971. Lẹ́yìn ọdún 77, èyí [èrò ìyàsọ́tọ̀] ò tí ì kúrò ní ìrònúu wa. Ilé-iṣẹ́ [tí ó ni ilé ìtajà Maxi] náà jẹ́ ti àwọn Dutch-Belgian ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn-an wa ni àwọn òṣìṣẹ́ẹ wọn! Ohun ìtìjú! Àtìlẹyìn fún obìnrin gidi àti òṣèré yìí @NatasaTasicKnez.

“Ta ni ó ń kọrin níbẹ̀ yẹn” jẹ́ eré Yugoslavia ayé ìgbà 1980 tí ó sì di ipò ẹgbẹ́-ìmùlẹ̀ láàárín àwọn Balkan. Nínú ìtàn náà, wọ́n ṣèṣì fẹ̀sùn olè kan àwọn olórin Roma méjì, orí ni ó kó wọn yọ lọ́wọ́ ìjìyà láìsí ìdájọ́.

Ilé-iṣẹ́ tí ó ni ilé ìtajà-ìgbàlóde Maxi, Delez Srbija, ṣe àgbéjáde àkọsílẹ̀ ìtúúbá lọ́jọ́ kan náà, ó sọ pé àwọn “gbàgbọ́ pé èyí á wà bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìyàsọ́tọ̀ tí ó mú ìfura ẹni tí kò yẹ dání pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò ní wáyé mọ́ lọ́jọ́ iwájú. Ilé-iṣẹ́ náà fi kún un pé àwọn á ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn lórí bí a ṣe ń hùwà bí wọ́n bá fura sí olè jíjà.

Ní ọjọ́ kejì, Miloš Nikolić tí ó jẹ́ adarí ọ́fíìsì tí ó ń ṣe àfikún Novi Sad mọ́ Roma sọ̀rọ̀ tako ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó ní; “gbogbo ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn ará Roma lọ́kùnrin lóbìnrin ni ẹ̀yà tí a yà sọ́tọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdèe wa. A ní láti ṣiṣẹ́ pọ̀ láti yí i padà!”

Ní 31 oṣù Ọpẹ, Igbá-kejì Alákòóso Ìgbìmọ̀ Ìjọba àti Ààrẹ Àjọ-tí-ó-ń-fètò-sí Ìmúdọ́gba Akọ-àtabo ní àwùjọ, Zorana Mihajlović náà sọ̀rọ̀ tako àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtajà Maxi pé “ìwà ìbanilórúkọjẹ́ ni wọ́n hù àti pé wọ́n jẹ̀bi”. Kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣe sí ìyàsọ́tọ̀ àwọn ọmọ Roma ní Serbia…

Bíótilẹ̀jẹ́pé ó dàbí ẹni pé arábìnrin Knežević ti yọ ara rẹ̀ kúrò lórí Facebook, bóyá láti lè jẹ́ kí ọ̀ràn náà ó silẹ̀, ó fi àlàyé-nípa-ara rẹ̀ orí Twitter sílẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ tí ó ṣíwájú Ọdún Tuntun, ó fi àtẹ̀jáde ṣókí sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ẹ̀ mi ọ̀wọ́n, ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò dùn mọ́ni nínú kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, ṣùgbọ́n mo nírètí pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ náà á pín pẹ̀lú ọdun 2018 àti pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò ní wáyé mọ́. Ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ènìyàn ẹlẹ́ran ara, ohun tí ó dára jù ní ayé yìí nìyẹn. <3

— NatasaTasicKnezevic (@NatasaTasicKnez) December 31, 2018

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.