- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

‘Ẹ Yé é Pa Àwọn Òbìnrin’ – ìpolongo tuntun tí ó ń tako ìjìyà inú ìgbéyàwó ní Angola

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Angola, Ìfẹ̀hónúhàn, Ìjàfúnẹ̀tọ́ Ẹ̀rọ-ìgbàlódé, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣèlú, Obìrin àti Akọtàbábo, Ọ̀dọ́, Òfin
Manifestação em Luanda: #Paremdematarasmulheres | foto Simão Hossi [1]

Ìfẹ̀hànnúhàn hàn ní Luanda, Angola, pẹ̀lú àmì ìpolongo #Paremdematarasmulheres ní èdè Portuguese, tabí ‘ẹ yé é pa obìrin’, àwòrán láti ọwọ́ọ  Simão Hossi, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Nígbà tí wọ́n bá òkú agbẹjọ́rò tí ó jẹ́ ẹni ọdún 26, Carolina Joaquim de Sousa da Silva nínú ilée rẹ̀ [2] ní ọjọ́ 3, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018, ọkọ rẹ̀ jẹ́wọ́ ọ̀ràn náà, ó sì di èrò àhámọ̀ ẹ̀ka tí ó ń ṣe ìwádìí ìwà ọ̀daràn ti Angola tí a mọ̀ sí SIC.

Láàárín ọ̀sẹ̀ kan náà, ìròyìn ikú obìnrin kan ni ó jáde láti ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Gbogboògbò orílẹ̀-èdè Angola tí ó ní wípé ọ̀rẹ́kùnrin ìgbà-kan-rí obìnrin náà ni ó gún un pa.

Àwọn ọ̀ràn ìwà ọ̀darànmọràn yìí ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ní orílẹ̀-èdè Angola dúró gírígírí, èyí sì fa ìpolongo tuntun kan tí ó ń tako ìjìyà abẹ́lé tí wọ́n pe àkóríi rẹ̀ ní “Ẹ Yé é Pa àwọn Obìnrin [3]” tí Ẹgbẹ́ Ondjango tí ó jẹ́ àjọ ajàfúnẹ̀tọ́ obìnrin tí kì í ṣe ti ìjọba ṣe àgbékalẹ̀ẹ rẹ̀. Wọ́n ṣe àmúlò Facebook gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìkórajọ wọn, èròńgbà wọn ni láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa àwọn ìjìyà obìnrin ní orílẹ̀-èdè Angola:

Estes têm sido dias difíceis. Na verdade, para nós mulheres, muitos dias são difíceis e dolorosos porque ainda vivemos em contextos onde se justifica quase sempre, de uma ou de outra forma, todo o tipo de violência contra nós. E nestes últimos dias, em particular, ficou tudo ainda mais penoso por termos de lidar com as reacções que vieram à tona depois do caso de Carolina…

A violência contra as mulheres é real, é mesmo. Não é coisa da cabeça de feministas, não é invenção ou discurso vazio: É REAL! Carolina, infelizmente só acrescentou as estatísticas, houveram muitos outros casos antes dela que vieram a público e existem milhares de outros casos que não vêm a público. É um problema que está aí à porta, aos nossos olhos. E é um problema que extrapola relações entre um ou outro casal: é um problema estrutural.

Há uma estrutura que dita e relega as mulheres a papéis de subalternização que as torna em potenciais alvos de violência de todos os tipos e a todos níveis. Esta estrutura de supremacia masculina que paira sobre nós e muitos negam existir, e que não é invisível, faz isto: mutila e destrói as vidas das mulheres e MATA!

Nós, mulheres singulares e também enquanto colectivo, vamos continuar a gritar ‘parem de nos matar’ e de ‘ferir a nossa existência’. Queremos leis que nos protejam e sejam aplicáveis de facto, queremos políticas públicas que tragam aos debates e às instituições o respeito da nossa humanidade. Queremos uma sociedade onde não tenhamos medo de sair à rua! Vamos continuar a reivindicar uma sociedade onde tenhamos as nossas liberdades de ser, de sentir, de andar e pensar como quisermos. Vamos continuar a reivindicar uma sociedade onde possamos viver em segurança.

Àsìkò yìí jẹ́ èyí tí ó le. Lóòótọ́, fún àwa obìnrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ni ó le tí ó sì ń dùn èèyàn nítorí pé a ṣì wà ní ipò tí ó jẹ́ pé a máa ń yẹra fún ìjìyà lọ́nà kan tàbí òmíràn. Láìpẹ́ yìí gan-an pàápàá, ó dunni láti máa kojú àwọn ìhùwàsí tí ó ń jáde lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ti Carolina…

Lóòótọ́ ni ìjìyà àwọn obìnrin, ó wà lóòótọ́. Kì í ṣe ohun tí ó kàn wá lórí àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ obìnrin, kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ àgbélẹ̀rọ tàbí ọ̀rọ̀ òfìfo, LÓÒÓTỌ́ NI! Ó ṣeni láàánú pé ti Carolina kún ìṣirò tí ó ti wà nílẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀ràn báyìí ti wáyé kí tirẹ̀ ó tó ṣẹlẹ̀ tí àwọn ènìyàn gbọ́ sí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀ràn mìíràn tí àwọn èèyàn ò mọ̀ sí, ó jẹ́ ìṣòro kan tí ó ti wà níbẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà níwájú wa. Ó sì jẹ́ ìṣòro tí ó ń ro ti ìbáṣe láàárín tọkọtaya – ìṣòro àtilẹ̀wá ni.

Ètò ìpìlẹ̀ kan wà tí ó ń pàṣẹ tí ó sì ń rẹ àwọn obìnrin sílẹ̀ sí ipò ẹ̀yìn tí èyí sì sọ wọ́n di olùfaragbá ìjìyà lóríṣiríṣi àti ní gbogbo ọ̀nà. Ètò fífi akọ ṣe olórí yìí tí ó ti kọ́ wa lọ́rùn tipẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ń kọ̀ pé kò rí bẹ́ẹ̀ – ìyẹn kò sì ṣe é rí – ohun tí ó ń ṣe rè é: ó ń sọni di aláàbọ̀-ara, ó ń ba ayé àwọn obìnrin jẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ń pani.

Àwa obìnrin lọ́kọ̀ọ̀kan àti àpapọ̀ọ wa, a máa tẹ̀síwajú láti máa pariwo kí ‘ẹ yéé pa wá’ kí ẹ sì ‘yéé ṣe wá léṣe’.

À ń fẹ́ àwọn òfin tí yóò dáàbò bò wá tí wọn yóò sì kún ojú ìwọ̀n, a fẹ́ àwọn ètò àmúlò gbogboògbò tí yóò mú àpọ́nlé wa lọ sí àwọn ìtàkùrọ̀sọ àti àwọn ìdásílẹ̀. A fẹ́ àwùjọ tí ẹ̀rù àtijáde ò ti ní bà wá! A máa tẹ̀síwajú láti béèrè fún àwùjọ tí a óò ti ní òmìnira ti ara, òmìnira ìmọ̀lára, òmìnira ìrìn àti òmìnira ríronú bí a ṣe fẹ́.

A máa tẹ̀síwajú láti béèrè fún àwùjọ tí a ti lè gbáyé pẹ̀lú ààbò tó péye.

Bẹ́ẹ̀, ìpolongo yìí mú èsì tí ó ń takoni wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n rí ìdí fún ìdáláre fún ìrúkèrúdò fífi ìyà jẹ obìnrin. Wọ́n pe ìpolongo wọn ní “Ẹ Yé é Dà Wá”, wọ́n gbà pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ jẹ́ ìdí tí ó tọ́ láti máa fìyà jẹ obìnrin. Bíótilẹ̀jẹ́pé èrò wọn ò tí ì máa rinlẹ̀, Olórin Angola, Gill Slows Allen Russell [4] náà sọ̀rọ̀;

Parem de trair os outros, por favor chegaaaaa de corno. É um grito de clamor, mulheres se não nos querem mais peçam divórcio antes de trair se não vão bazar mesm.

“Ẹ yé é da ẹlòmíràn, ẹ jọ̀wọ́ a ò fẹ́ aláìṣòdodo aya mọ́. À ń ké tantan, ẹ̀yin obìnrin bí ẹ kò bá nífẹ̀ẹ́ wa mọ́, ẹ béèrè fún ìtúká kí ẹ tó máa dà wa, ẹ máa lọ.

Onímọ̀ àwùjọ Mbangula Kemba [5] sọ̀rọ̀ tako ojú tí wọ́n fi wo ọ̀rọ̀ yìí, ó tẹnumọ́ọ pé wọn ò gbọdọ̀ fi ìfìyàjẹni yanjú ìṣòro nínú ìgbéyàwó.

Angola fi ìdí òfin tí ó ń de ìfìyàjẹni tí wọ́n mọ̀ sí 25/11 múlẹ̀ ní ọdún 2011 tí ó ń sọ onírúurú ìfìyàjẹni abẹ́lé di ìwà ọ̀daràn ní gbangba. Síbẹ̀síbẹ̀, ìdájọ́ òfin yìí kò le tó, ìtìmọ́lé ọdún méjì sí mẹ́jọ.

Sizaltina Cutaia [6], tí í ṣe ajìjàǹgbara àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin ní Angola; tí ó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká fún iṣẹ́ẹ rẹ̀ lórí ẹ̀tọ́ obìnrin béèrè fún ìṣàmúlò òfin náà lórí àwọn gbàgede ìtàkùrọ̀sọ lórí ẹ̀rọ-alátagbà:

Não basta só agravar as penas, senhora Vice Presidente do MPLA, é preciso que o Estado crie estruturas condições para combater a violência, os compromissos assumidos em 2007 por via da ratificação do protocolo de Maputo precisam de ser efectivados. Para além disso, há que criar estruturas para atender as vítimas e enact legislação complementar que garanta de facto a realização dos direitos das mulheres. Isso inclui toda a legislação em torno dos direitos sexuais e reprodutivos das mulheres.

Não adianta fazer discurso contra a violência doméstica e depois apoiar políticas que autorizem os fiscais e polícias diariamente agridam mulheres nas rua, é contraditório!

Não adianta fazer discurso contra a violência doméstica e apoiar um OGE que não acautele os serviços sociais cujo subfinanciamento todas sabemos impacta negativamente a vida das mulheres. É preciso dar sentido aos discursos com accoes concretas. Put the money where the mouth is.
#paremdematarasmulheres [7]

Àfikún ọdún ẹ̀wọ̀n kò tó, arábìnrin igbá-kejì Ààrẹ MPLA [Àjọ Àwọn ènìyàn tó fẹ́ ìdásílẹ̀ Angola], Ó nílò kí orílẹ̀-èdè ṣe ìdásílẹ̀ àwọn ìlànà àtilẹ̀wá tí yóò kojú ìpanilára – Àwọn ohun tí wọ́n fara mọ́ ní 2007 nípa àjọsọ ìlànà Maputo ní láti di ṣíṣe. Bákan náà ni ti èyí, ó nílò kí wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ òfin arọ́pò tí yóò mú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin rinlẹ̀. Lára èyí ni gbogbo òfin tí ó de obìnrin ní ti ìbálòpọ̀ àti ẹ̀tọ́ ọmọ bíbí wà.

Kò sí ìwúlò ìsọ̀rọ̀ tako ìjìyà abẹ́lé kí ó wá di ẹ̀yìn wá kí a máa ṣe ìgbèlẹ́yìn àwọn òfin tí ó fi àṣẹ fún agbófinró láti yẹ̀yẹ́ obìrin ní títì ní ojúmọ́, kò bá ara mu!

Kò wúlò kí a máa sọ̀rọ̀ tako ìjìyà abẹ́lé kí a sì tún máa gbèlẹ́yìn àṣàrò ìnáwó tí kò ní ṣe ààbò ètò àwùjọ, ìṣúná àìtó tí gbogbo wa mọ̀ pé ipa òdì ni ó ń kó nínú ayé àwọn obìnrin. Ó ṣe pàtàkì kí a fi ọgbọ́n kún àwọn ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ṣíṣe gidi. Ẹ fi owó yín sí ibi tí ẹnu yín wà.

#ẹyéépaàwọnobìnrin

Ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin Cecelia Kitombé [8] sọ̀rọ̀ sí àwọn tí ó ń ṣe àtìlẹyìn ìbáṣepọ̀ tí ó níyà nínú:

Alguns dos que estão a dizer e a escrever textão contra violência as mulheres afirmando que está demais, são os mesmos que aconselham as filhas, irmãs e primas a continuarem em relações abusivas, sob pretexto de que na conversa de marido e mulher não se mete a colher, outros ainda te dizem continue, a vida a dois é mesmo assim… Há ainda aqueles que acham que a mulher pode tudo, mas nunca esquecer o seu “papel”…

Parem de nos matar!!!

Lára wa tí à ń tẹnumọ́ ọn pé ó pọ̀jù [láti sọ̀rọ̀ síta tako ìjìyà Abẹ́lé] náà ni ẹni tí ó ń gba àwọn ọmọbìnrin, arábìnrin àti ìbátan lóbìnrin níyànjú láti máa fi ara da ìbáṣepọ̀ tí ó ń pani lára pẹ̀lú ọ̀rọ̀-ẹ̀tàn pé ọ̀rọ̀ tọkọtaya ò ṣe é dá sí, àwọn mìíràn á ní kí o tẹ̀síwajú bẹ́ẹ̀, bí ọ̀rọ̀ lọ́kọláya ṣe rí nìyẹn… Àwọn kan tilẹ̀ rò pé obìnrin lè ṣe gbogbo nǹkan, ṣùgbọ́n wọn ò gbọdọ̀ gbàgbé ‘ojúṣe’ wọn.

Ẹ yéé pa wá!!!