100 ọjọ́ fún Alaa: Ẹbí ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọ Íjípìtì ń ka ọjọ́ fún ìdásílẹ̀ẹ rẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n

Alaa Abd El Fattah, àwòrán láti ọwọ́ Nariman El-Mofty.

Lẹ́yìn tí ó ti lo ọdún 5 nínú ẹ̀wọ̀n, akọbúlọ́ọ̀gù ọmọ Íjípìtì àti ajàfúnẹ̀tọ́ Alaa Abd El Fattah yóò gba ìdásílẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n ní ọjọ́ 7, oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún 2019. Ní ọjọ́ 8 oṣù Ọ̀pẹ, ẹbíi rẹ̀ ti  ṣe àgbékalẹ̀ ìpolongo –“100 ọjọ́ fún Alaa” — kí àtìmọ́lée rẹ̀ ó ba wá s'ópin ní mọnawáà.

Ìdásílẹ̀ẹ rẹ̀ nínú oṣù Ẹrẹ́nà kì í ṣe ìsààmì òpin ìgbà Alaa ní ẹ̀wọ̀n, ṣùgbọ́n ìṣíkúrò sí ipò tí ó jẹ́ àṣekágbá àtìmọ́lée rẹ̀. Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ẹ rẹ̀, Alaa yóò máa wá sun oorun alẹ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá ìbílẹ̀ẹ rẹ̀ fún àfikún ọdún márùn-ún gbáko. Abẹ́ ìṣọ́ ọlọ́pàá ni yóò wà fún àkókò yìí.

A fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú Alaa a sì mú u kúrò ní ilé ẹbíi rẹ̀ nínú oṣù Belu ọdún 2013. Ọdún kan kọjá, nínú oṣù Èrèlé ọdún 2015, a gbé e re ilé ẹjọ́ a sì rán an ní ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún fún “àgbékalẹ̀” ìyíde kiri ìfẹ̀hànnúhàn lábẹ́ òfin ìyíde kiri ìfẹ̀hànnúhàn ọdún 2013 tí kò fi àyè gba ìyíde láìgbàṣẹ. Ní tòótọ́ ni ó kópa nínú ìyíde kiri tí ó ń tako ẹjọ́ tí àwọn ológun dá mẹ́kúnnú ní ọjọ́ 26 oṣù Belu ọdún 2013, Alaa kò kó ipa nínú àgbékalẹ̀ẹ rẹ̀. Ilé ẹjọ́ Cassation ti Íjípìtì fi ẹsẹ ẹ̀wọ̀n-ọn rẹ̀ múlẹ̀ nínú oṣù Belu ọdún 2017.

Omar Robert Hamilton, olùkùu Alaa, to àwọn ète ìpolongo náà lẹ́sẹẹsẹ lóríi Twitter:

  1. Láti mú kí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ àti ọmọ àgbáyé ó fi ọkàn sí ìdájọ́ àti fún ìdásílẹ̀ẹ Alaa ní ọjọ́ 17 oṣù Ẹrẹ́nà.
  2. Láti gbé ìrò المراقبة (‘ìṣọ́nikiri’ tàbí ‘ìdásílẹ̀-lẹ́wọ̀n-kọ́jọ́-ìdásílẹ̀-tó-pé’) sínú làákàyè àwọn ènìyàn gbogbo. Lẹ́yìn ìdásílẹ̀, Alaa ṣì tún ní láti sun ọrùn alẹ́ nínú àgọ́ ọlọ́pàá ìbílẹ̀ẹ rẹ̀ fún “ọdún márùn-ún”. A ní láti ṣe iṣẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìtako èyí.

Gbogbo olórí orílẹ̀-èdè Íjípìtì ni ó ti ṣe ìwádìí tàbí rán Alaa ní ẹ̀wọ̀n ní ojú ayée rẹ̀. Ní ọdún 2006, a fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú u fún ipa tí ó kó nínú ìyíde kiri ìfẹ̀hànnúhàn tí kò fa ìdíwọ́ fún ẹnikẹ́ni. Ní ọdún 2011, ó lo oṣù méjì ní ẹ̀wọ̀n, àkókò yìí ni ìyàwóo rẹ̀ bí àkọ́bíi rẹ̀, Khaled. Ní ọdún 2013, a mú u a sì fi sínú àhámọ́ fún ọjọ́ 115 láì ṣe ìgbẹ́jọ́.

Ó ti pẹ́ tí Alaa ti ń ṣiṣẹ́ lóríi ìjìnlẹ̀ ìmọ̀-ẹ̀rọ àti òṣèlú pẹ̀lú ìyàwóo rẹ̀, Manal Hassan. Ìdílé gbajúgbajà ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni ó ti wà, adájọ́ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn Ahmed Seif El Islam, ni bàbáa Alaa, ẹni tí a ti rán lọ ní ẹ̀wọ̀n láì mọye ìgbà ní abẹ́ àṣẹ Hosni Mubarak. Ẹ̀gbọ́n-bìrin méjèèjì Abd El Fattah, Mona àti Sanaa Seif, jẹ́ agbèjà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn bákan náà tí wọ́n sì ti ṣe ìpolongo alátakò ìjìyà mẹ́kúnnú lọ́wọ́ọ àwọn ológun ní ìlú náà. Ní ọdún 2016, Sanaa lo oṣù mẹ́fà ní ẹ̀wọ̀n nítorí wípé ó sọ̀rọ̀ àfojúdi sí alaṣẹ ìjọba.

Àdánwòo Alaa jọ ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Íjípìtì tí ó wà ní ẹ̀yin gádà nítorí akitiyan wọn nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Ẹgbẹ́ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn sọ wípé, àwọn tí ìjọba rán ní ẹ̀wọ̀n ní Íjípìtì á tó 60,000. Gbogbo ẹni tí ìjọba bá fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú ní Íjípìtì ní í jẹ ìyà oró, ìfarasin, àtìmọ́lé ọjọ́ pípẹ́ àti àdánìkangbé inúu túbú.

Dídarapọ̀ mọ́n ìpolongo #FreeAlaa

Ní inú ìwé tí a kọ sí àwọn àlejò tí ó wá sí RightsCon, àpérò tó dá lórí ẹ̀tọ́ irinṣẹ́ ẹ̀rọ-ayárabíaṣá tí ó wáyé ní Toronto nínú oṣù Èbìbì ọdún 2018, Alaa rọ àwọn alátìlẹ́yìn láti “ṣe àtúnṣe sí ìjọba àwa-arawa ti wọn”.

Èyí ti fi ìgbà pípẹ́ jẹ́ ìdáhùn mi sí ìbéèrè náà “báwo ni a ṣe lè ṣe ìrànwọ́?” Mo ṣì ní ìgbàgbọ́ wípé [àtúnṣe ìjọba àwa-arawa] ni ìdáhùn kan ṣoṣo. Kì í ṣe ibi tí ò ń gbé nìkan, ṣiṣẹ́, san owó orí àti ṣe àkóso ibi tí ó ti ní ipa, àmọ́ ìfàsẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nínú ibi tí ìjọba àwa-arawa ti fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ lè di lílò fún ìrúfin ẹ̀tọ́ ní àwọn agbègbè tí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kò fi bẹ́ẹ̀ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀. Mo mọ̀ wípé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní òde òní jẹ́ ẹ̀rí wípé àtúnṣe pọ̀ láti ṣe. Mo ń retí ìmísí ọ̀nà tí ẹ ó gbà tún un ṣe.

Kí ẹni tí ó bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ìpolongo “100 ọjọ́ fún Alaa” ó fi “àròkọ, àwòrán tàbí ìṣe ìlọ́wọ́sí ìpolongo” ṣọwọ́ tí a lè tún tẹ̀ jáde sórí ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé ìpolongo náà:

Ìpolongo orísun-ọ̀fẹ́ – a óò máa tẹ àwọn ọgbọ́n àtinúdá tuntun síta, àmọ́  a nílò láti gba èrò tuntun àti agbára tuntun wọlé bákan náà. Torí ìdí èyí máa bá wa ronú!

Bí ìgbà gbogbo, àmì ìpolongo ni #FreeAlaa – jọ̀wọ́ darapọ̀ mọ́ wa fún ìpalẹ̀mọ́ ìdásílẹ̀ẹ Alaa.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.