Ìjàm̀bá Àwọn Ológun Mauritania 28 tí wọ́n pa ní ọjọ́ Òmìnira tí a kò sọ

Àwòrán àwọn Ológun 28 tí wọ́n pa lọ́jọ́ òmìnira – Ibrahima Sow ni ó ṣe àtẹ̀jáde fídíò.

Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Belu ọdún 1990,  àwọn ẹgbẹ́ ológun yẹgi fún ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n tí a fi ìfarabalẹ̀ ṣà lọ́kọ̀ọ̀kan láti pa nínú ẹ̀wọ̀n láàárín òru, ní Inal ní orílẹ̀-èdè Mauritania lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn ìpète-lati-gba-ìjọba kàn wọ́n.

Ọjọ́ yìí, tún jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ tí orílẹ̀-èdè Mauritania gba òmìnira lọ́wọ́ France ní ọdún 1960, lé góńgó sọ́kàn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mauritania kan tí wọ́n ń wá ìdájọ́ òdodo fún ìpakúpa tí wọ́n pa àwọn ọkùnrin 28 yìí, tí gbogbo wọn sì jẹ́ aláwọ̀ dúdú.

Orílẹ̀-èdè Mauritania ti Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀  jẹ́ ìdàpọ̀ àwọn Lárúbáwá àti àwọn aláwọ̀ dúdú, àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn sọ pé àwọn aláwọ̀ dúdú ti ń dojúkọ ìyàsọ́tọ̀ àti ìlòkulò fún ìgbà pípẹ́.

Ààrẹ Ìgbìmọ̀ àwọn Inal-France, Youba Dianka, ṣàlàyé:

Je tiens à préciser qu’Inal n’est qu’un exemple; il y a eu plusieurs Inal en Mauritanie. Des horreurs ont eu lieu à Azlatt, à Sory Malé, à Wothie, à Walata, à Jreida et dans toute la vallée. A l’intérieur de la caserne militaire d’Inal et environs, il y a eu des militaires écartelés, enterrés vifs, tués à bout portant, et pendus pour célébrer la fête de l’indépendance du pays en 1990.

“Mo fẹ́ fi hàn wípé àpẹẹrẹ ni Inal jẹ́; ọ̀pọ̀ ọmọ ‘Inal’ ni ó ti wà ní Mauritania. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abanilẹ́rù ti wáyé ní Azlatt, Sony Malé, Wothie, Walata, Jreida àti nínú àfonífojì. Nínú ọgbà àwọn ológun ní Inal àti àgbègbè rẹ̀, wọ́n pín àwọn ológun yẹ́lẹyẹ̀lẹ, wọ́n rì wọ́n mọ́lẹ̀ ní òòyẹ̀,  wọ́n yìnbọn lù wọ́n, wọ́n sì yẹgi fún wọn ní ìrántí òmìnira orílẹ̀-èdè náà lọ́dún 1990.

Ní àyájọ́ ọjọ́ òmìnira ti ọdún yìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mauritania fi ọkàn sí yíyàn tí a yan ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè wọn sí àṣekágbá ìdíje Ife-ẹ̀yẹ ti àwọn orílẹ̀-èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (CAF) ju bí wọ́n ṣe ṣe sí àwọn ẹni ìgbàgbé, “àwọn ológun tí wọ́n wà nínú kòtò àìmọ̀… tí wọ́n ṣì ń dúró de ìsìnkú tí ó yẹni“, Kaaw Elimane Bilbassi Toure tí í ṣe olóòtú ibùdó ìròyìn orí ayélujára Le Flambeau ti Mauritania kọ.

Kiné-Fatim Diop, adarí ìpolongo Amnesty International ní Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀, sọ̀rọ̀ ní ọdún yìí nípa ìtakora tí ó wà ní àárín ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ ọjọ́ ìṣèrántí-dunnú àti ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí àwọn olùfarapa ń rò:

Chaque année, pendant que les officiels célèbrent dans la joie l’accession à la souveraineté du pays, les familles des victimes pleurent et manifestent dans la tristesse pour demander justice et réparation. Face à elles, les autorités mauritaniennes s’efforcent d’ensevelir cette face hideuse de l’histoire, comme lorsqu’elles faisaient voter, en catimini en 1993, une loi d’amnistie confirmant l’amnésie de l’État sur les tueries des militaires il y a 30 ans.

Lọ́dọọdún, bí àwọn tí wọ́n dipò mú ṣe ń ṣe ìrántí ìgùnkè wọn sí ipò gíga pẹ̀lú ìdùnnú, ẹbí àwọn olùfarapa máa ń sunkún, tí wọ́n sì máa ń fi ẹhónú hàn pẹ̀lú ìbànújẹ́ fún àtúnṣe àti ìdájọ́ òdodo. Àwọn tí ó wà nípò àṣẹ kàn ń gbìyànjú láti ri apá òmìnira tí kò farahàn yìí mọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe dìbò yan òfin ìdáríjì ìjọba ní ìkọ̀kọ̀ lọ́dún 1993 tí wọ́n sì fìdí ìgbàgbé ìjọba múlẹ̀ nípa ìpakúpa àwọn ológun náà lọ́gbọ̀n ọdún sẹ́yìn.

Àjọ tí ó ń tako àìjìyà ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àìṣòdodo ní orílẹ̀-èdè Mauritania Forum Against Impunity and Injustice fi ìbànújẹ́ hàn lórí ìjàm̀bá àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan tí a yẹgi fún lálẹ́ ọjọ́ burúkú Èṣù gb'omi mu yìí.

Absolument, une malédiction gratuite s’était battue sur les 28 officiers noirs ce soir-là. Telle la pendaison de deux frères Diallo Oumar Demba et son frère Diallo Ibrahima qui portaient des numéros successifs écrits par le moyen d’un feutre. Triste mort que celle d’assister placidement à la mort de son frère aîné. Les bourreaux tuaient avec précision, d’ailleurs, ils ne se limitaient pas seulement-là, ils trainaient les pendus et s’asseyaient sur leur cadavre.

Láìsí àní-àní, èpè ja àwọn ológun 28  yẹn lóru ọjọ́ náà. Bí i ti àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Diallo Oumar Demba àti àbúròo rẹ̀ Diallo Ibrahima tí a yẹgi fún pẹ̀lú àkọsílẹ̀ nọ́ḿbà tí ó tẹ̀lé ara wọn tí a fi gègé kọ sí wọn lára. Ohun tí ó mú èyí bani nínú jẹ́ jù ni fún ẹni láti rí ikú tí ó pa ẹ̀gbọ́n ẹni. Àwọn apani ṣe iṣẹ́ wọn pé, wọn kò sì dáwọ́ dúró lẹ́yìn tí wọ́n yẹgi fún wọn, wọ́n tún wọ́ òkúu wọn nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ń jókòó lé wọn lórí.

Àwọn Ẹni-orí-kó-yọ sọ̀rọ̀ síta

Ẹ̀rí túbọ̀ ń tẹnu àwọn ẹni-orí-kó-yọ jáde lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún.

Mamadou Sy jẹ́ apàṣẹ ẹgbẹ́-ológun nínú ẹgbẹ́ ológun Mauritania, ó ti jẹ́ igbákejì apàṣẹ, kí ó tó wá di apàṣẹ ẹgbẹ́ ológun ẹ̀ka kan kí wọ́n tó mú un ní alẹ́ ọjọ́ yẹn.

Nínú ìwée rẹ̀, “Ọ̀run-àpáàdì ní Inal“, tí a tẹ̀ jáde ní ọdún 2000, ó ṣàpèjúwe ìjìyà-oró tí ó jẹ, nígbà tí àwọn apàṣẹ ológun dì í lójú, so ó mọ́lẹ̀, tí wọ́n sì jù ú sínú omi ìdọ̀tí rírùn.

Ológun mìíràn tí orí kó yọ lálẹ́ ọjọ́ burúkú yìí tiraka gba France lọ fún ìtọ́jú lẹ́yìn tí ó kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn Àjọ Onígbàgbọ́ tí ó ń tako Ìfìyàjẹni (ACAT lédè Faransé). Ní ipò àìlórúkọ, ó jẹ́rìí sí ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà tí ó rí láàárín ọdún mẹ́rìnlélógún tí ó fi ṣiṣẹ́ ológun:

Aussi loin que je remonte dans ma vie, depuis que j´ai commencé à comprendre, j´ai toujours constaté que les noirs n´avaient aucun droit, et que les Maures blancs étaient privilégiés. Chez nous, sur vingt ministres au gouvernement il y a un quart seulement pour les noirs, à l´armée, un seul Noir pour dix officiers. Dans un stage, si un Maure a mal travaillé, il l'emporte portant sur n´importe quel Noir. Et pas question de protester…

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe rántí, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi, mo ti máa ń ṣàkíyèsí pé àwọn aláwọ̀ dúdú kì í ní ẹ̀tọ́ kankan, ṣùgbọ́n àwọn aláwọ̀ funfun ará Mauritania máa ń ní àǹfààní tí ó pọ̀. Níbí, nínú ogún àwọn adarí ipò ìjọba, ìdá mẹ́rin péré ni wọ́n jẹ́ aláwọ̀ dúdú. Nínú ẹgbẹ́ ológun, aláwọ̀ dúdú kan ṣoṣo ni ó máa ń wà láàárín ológun mẹ́wàá. Nígbà ìkọ́ṣẹ́, bí ọmọ Mauritania aláwọ̀ funfun kan kò bá ṣe dáadáa, wọn á ṣì borí aláwọ̀ dúdú mìíràn. A ò sì gbọdọ̀ fi ẹhónú hàn…

Ó ṣe àpèjúwe àwọn ìfìyàorójẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ológun mìíràn rí:

Par exemple, on creusait des trous dans le sable, on nous enterrait jusqu´au coup, la tête immobilisée, le visage nu tourné vers le soleil. Si on essayait de fermer les yeux, les gardes nous y jetaient du sable. Ensuite on nous remettait nos bandeaux.

Fún àpẹẹrẹ, wọ́n gbẹ́ kòtò sínú iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì rì wá mọ́lẹ̀ dé ibi ọrùn, orí wa ò ṣe é yí, ojú wa sì wà ní ìhà oòrùn. Tí a bá sì gbìyànjú láti pa ojú dé, àwọn ẹ̀ṣọ́ á da iyẹ̀pẹ̀ sí wa. Wọ́n á sì wọ ìbòjú padà.

Maimouna Alpha Sy, akọ̀wé gbogboògbò fún Ẹgbẹ́ Ọ̀ràn Opó àti Aṣàánù ọmọ-ènìyàn, ti fi ìgbà kan rí jẹ́ aya Ba Baïdy Alassane, tí ó jẹ́ adarí àwọn ẹ̀ṣọ́ ibodè tẹ́lẹ̀. Alpha Sy sọ pé ọkọ rẹ̀ tí ó ti di olóògbé wà lára àwọn tí wọ́n pa lọ́dún 1990.

Maimouna Alpha Sy, general secretary of the Widow and Humanitarian Issues Association , was once married to Ba Baïdy Alassane, a former customs controller. Alpha Sy says her late husband was among the victims killed in 1990.

Nous avons fait trois mois et dix jours à la recherche de mon mari sans pouvoir le retrouver … La Douane nous a dit qu’il est mort d’un arrêt cardiaque, ce qui n’est pas vrai. Il y a des témoins qui ont été arrêtés, ligotés et torturés avec lui. Il a été tué devant ces gens-là.

Oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ni a fi wá ọkọ mi, ṣùgbọ́n pàbó ni ó já sí… Àwọn ẹ̀ṣọ́-ibodè sọ fún wa pé àìsàn ọkàn ló pa á, tí èyí kò sì jẹ́ òtítọ́. Wọ́n mú àwọn tó jẹ́rìí pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n so wọ́n, wọ́n sì fi ìyà oró jẹ wọ́n pẹ̀lú rẹ̀. Ní iwájú wọn ni wọ́n ti pa á.

‘Kò tún gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ mọ́’

Lọ́dún yìí ni ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, àwọn ọmọ Mauritania tí wọ́n jẹ́ aṣíkiri fi ẹ̀hónú hàn níwájú Ẹ́mbásì Mauritania ní ìlú Paris, ní orílẹ̀-èdè France, lórí àìfiyèsí ìjọba nípa ìṣẹ̀lẹ̀ oró yìí.

Kardiata Malick Diallo, tí ó jẹ́ igbákejì, sọ ọrọ àròjinlẹ̀ ní ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin Mauritania láti máà jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbàgbé, tí ó sì fi ẹ̀sùn kàn ààrẹ tí ó wà lórí oyè pé ó ń dáàbò bo àwọn oníṣẹ́-ibi náà, tí wọ́n ṣì ń dipò gíga mú nínú ìjọba nígbà tí wọn kò tí ì wá nǹkan ṣe sí ẹ̀tọ́ àwọn olùfarapa:

Même si votre pouvoir ne peut être tenu comme directement responsable de ces actes qui ont définitivement souillé le 28 novembre, il n’en demeure pas moins qu’il avait la charge de trouver une solution adéquate basée sur le droit des victimes à la vérité et à la justice … Les grandes nations et les grands peuples ne cherchent jamais à gommer un épisode sombre de leur histoire mais le matérialisent par des symboles visibles pour les maintenir dans la mémoire afin de dire « PLUS JAMAIS CA ». M. le Premier ministre, votre pouvoir a préféré poursuivre et parachevé un processus de marginalisation et d’exclusion.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kọ́ ni o ṣe iṣẹ́-ibi tí ó kó àbààwọ́n ba gbogbo ọjọ́ 28 oṣù Belu jẹ́, ìwọ ni ó yẹ kí o wá ojútùú sí ẹ̀tọ́ àwọn olùfarapa sí òtítọ́ àti òdodo… Àwọn orílẹ̀-èdè olókìkí àti àwọn èèyàn ńlá kì í gbìyànjú láti pa ìṣẹ̀lẹ̀ aburú inú ìtàn-an wọn rẹ́, dípò èyí wọ́n máa ń fi han ayé kí gbogbo ènìyàn lè rántí kí wọ́n sì sọ pé “KÒ TÚN GBỌDỌ̀ ṢẸLẸ̀ MỌ́’. Ọ̀gbẹ́ni ààrẹ, àkósoò rẹ ti ṣe àmúlò òfin ìyàsọ́tọ̀ àti ìyọkúrò ẹ̀yà.

Ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2018, nínú àwọn adarí ipò ìjọba 24, márùn-ún péré ni àwọn tí ó jẹ́ aláwọ̀ dúdú àti elẹ́yà-méjì, tí wọ́n ń ṣojú ìdá 70 àwọn mẹ̀kúnù. Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnù ni wọ́n kò ní aṣojú láàárín àwọn aṣojú tí wọ́n dìbò yàn, láàárín àwọn ẹgbẹ́ àbò àti àwọn adarí ipò ìjọba ìbílẹ̀.

Mauritania ni orílẹ̀-èdè tí ó gbẹ́yìn láti pa òwò-ẹrú rẹ ní àgbáyé ní ọdún 1981, ṣùgbọ́n wọn kò fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ títí di ọdún 2007, ìdá 20 àwọn ènìyàn ni wọ́n ṣì ń gbáyé ìṣẹrúsìn tí púpọ̀ nínú wọn sì jẹ́ aláwọ̀ dúdú tàbí elẹ́yà-méjì.

Nítorí ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà yìí ṣì ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Mauritania, ìdájọ́ òdodo kò sí ní àrọ́wọ́tó fún àwọn ẹni orí-kó-yọ àti àwọn ìdílé wọn.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.