Ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára ti ń rí ìfúnpa láti ọwọ́ ìjọba díẹ̀ díẹ̀. Nínú ìlànà òfin àti ọ̀rọ̀ Ajé, iye òmìnira ọ̀rọ̀ ń dìde kárí Ilẹ̀-Adúláwọ̀.
Nígbà tí àwọn ìjọba kan mọ rírì ètò ìjọba àwa-arawa nípasẹ̀ ṣíṣe ìbò pẹ̀lú ọlọ́pọ̀-ẹgbẹ́ òṣèlú àti sọ nígbangba nípa àjọṣe, nínú ìṣe, ọ̀pọ̀ máa ń lo àṣẹ tí ò ṣe é yí padà — wọ́n sì ń lo agbára àṣẹ yìí lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá bí ọjọ́ ṣe ń gun orí ọjọ́.
Cameroon, Tanzania, Uganda, Ethiopia, Nigeria, àti Benin ti ní Ìtìpa Ẹ̀rọ-ayélujára, ìjọba ti fi owó-orí lé lílo búlọ́ọ̀gù àti ẹ̀rọ-alátagbà, wọ́n sì ti fi ọwọ́ ṣìgún òfin mú oníròyìn. Òṣìṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ọmọ-ìlú ti di èrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn àtẹ̀jáde “ìròyìn irọ́” títí kan ìkóròyìn ìkòkọ̀ ìlú sí etí ìgbọ́ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò.
Ní ibi Àpérò Òmìnira Ẹ̀rọ-ayélujára ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (FIFA) tí ó wáyé ní Accra, Ghana, ikọ̀ akópa láti àwọn ìlú ilẹ̀ Adúláwọ̀ pátá sọ wípé kò ní ṣe ẹnu rere bí ìjọba bá fi òfin de ọmọ-ìlú tí ó ń lo ẹ̀rọ-ayárabíaṣá.
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ní àwọn òfin àti àbádòfin tí ó fún ọmọ ènìyàn ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ní Nàìjíríà, fún àpẹẹrẹ, Àbádòfin Òmìnira Ọ̀rọ̀ fún ọmọ ìlú ní òmìnira láti béèrè fún ìwífun lọ́wọ́ àjọ ìjọba. Abala 22 ìwé òfin ọdún 1999 pèsè fún ẹ̀tọ́ òmìnira ìròyìn àti Abala 39 fi lélẹ̀ wípé “gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, títí kan òmìnira láti gbá ìròyìn mú àti gba ọgbọ́n àti ìwífun láì sí ìdíwọ́…”
Síbẹ̀, Nàìjíríà tí tẹ àwọn òfin kan tí ó tẹ orí àwọn ẹ̀tọ́ òkè yìí bọlẹ̀.
Abala 24 Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára fi ẹ̀sùn kan “ẹnikẹ́ni tí ó bá tan iṣẹ́-ìjẹ́ tí kò ní òótọ́ kan nínú, tí ó lè fa ìbínú, ìnira, ewu, ìdíwọ́, àfojúdi, ìdáyàfò ọ̀daràn, ọ̀tá, ìkórìíra, tàbí ìbínú láì ní ìdí sí ẹlòmíràn ká tàbí fa kí a fi irúfẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́.”
Ìṣòfin àìdájú àti àwọn gbólóhùn bíi “ìnira” tàbí “ìwọ̀sí” jẹ́ nǹkan tí a ní láti mójútó. Ìjọba àti àwọn àjọ rẹ̀ máa ń sábà fi èyí ṣe bójúbójú fún ìtẹríbọlẹ̀ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.
Ta ni ẹni tí ó ń sọ bóyá ọ̀rọ̀ kan jẹ́ àfojúdi? Ǹjẹ́ ó yẹ kí òṣìṣẹ́ ìjọba ó ṣe ìmúdàgbà àwọ̀-ara tí ó ní ipọn? Ní àgbáyé, ọmọ-ìlú ní ẹ̀tọ́ láti wá àìṣedéédé aláṣẹ ìjọba. Kí ló dé tí Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka tí ó ṣe pàtàkì nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ?
Ní ọdún 2017 àti 2016, oníròyìn orí-ayélujára ọmọ bíbí ìlú Nàìjíríà àti akọbúlọ́ọ̀gù Abubakar Sidiq Usman àti Kẹ́mi Olúnlọ́yọ̀ọ́ tí ta ẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin nípasẹ̀ ṣíṣe iṣẹ́ ìkóròyìnjọ lóríi Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára.
Máà jìyà nínú ìdákẹ́rọrọ — máa wí lọ
Ìwà tí ó jẹ́ gbòògì àwọn ìpèníjà wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi ti òfin ń sọ fún ọmọ-ìlú pé ohùn-un wọn ṣe kókó. Kí a mú un láti Ìdádúró Tanzania tí ó dá lóríi ìtànká “ìròyìn irọ́, ìtànjẹ, tàbí ìròyìn tí ò pé ojú òṣùwọ̀n” lórí ayélujára títí kan owó-orí Uganda fún ìlò ẹ̀rọ-alátagbà fún ìgbógunti “àhesọ”, ariwo orí ẹ̀rọ-ayárabíaṣá ń já àwọn ìjọba aninilára láyà. Ní ìgbà mìíràn, ó máa mú wọn pa àwọn ìwàa wọn tì.
Ìrírí akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 ìlú Ethiopia jẹ́ àpẹẹrẹ.
Ní ọdún 2014, àwọn òǹkọ̀wé ọmọ bíbí Ethiopia mẹ́sàn-án lọ sí ẹ̀wọ̀n àti jìyà oró látàrí iṣẹ́ àjọṣepọ̀ tí wọ́n jọ kọ nípa ìtẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn ìjọba àná ìlú Ethiopia, kí òótọ́ ó di mímọ̀. Ìjọba pe ẹgbẹ́ yìí ni “afẹ̀míṣòfò” nítorí àtẹ̀jáde orí ẹ̀rọ-ayélujára wọn a sì ti wọ́n mọ́lé fún oṣù 18.
Àwọn mẹ́fà lára àwọn ẹgbẹ́ náà tí ó ti gba òmìnira báyìí ṣe ìtàkùrọ̀sọ àgbáyé àkọ́kọ́ ní ìlú Ghana ní àsìkò àpérò FIFA: Atnaf Berhane, Befeqadu Hailu Techane, Zelalem Kibret, Natnael Feleke Aberra, àti Abel Wabella náà wá sí àpérò. Jomanex Kasaye, ẹni tí ó ti bá ẹgbẹ́ náà ṣiṣẹ́ kí àtìmọ́lé ó tó ṣẹlẹ̀ (àmọ́ tí a kò fi àṣẹ mú) náà kò gbẹ́yìn níbi àpérò.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ẹgbẹ́ yìí ti bá Ohùn Àgbáyé ṣe pọ̀ láti kọ àti ṣe ìtúmọ̀ ìròyìn sí èdè Amharic. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé ṣe ìpolongo àti ìpanupọ̀ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àgbáyé gẹ́gẹ́ bi agbẹnusọ láti ọjọ́ tí wọ́n dé akoto ọba.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tí a tẹ ọ̀kanòjọ̀kan ìròyìn jáde àti ìgbélárugẹ ìtàkùrọ̀sọ ọ̀ràn wọn lórí Twitter, ìdálébi ìfàṣẹmú àti àtìmọ́lé gba ojúlé ìjọba àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní àgbáyé kọjá, láì gbàgbé àwọn ọgọọ́gọ̀rún àti ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún alátìlẹ́yìn orí ẹ̀rọ-ayélujára. Láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, igbe ńlá ni ó gba àwọn akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Ethiopia.
Nínú ọ̀rọ̀ wọn ní FIFA, àwọn akọbúlọ́ọ̀gù náà sọ wípé ìkẹ́gbẹ́ẹ wọn nínú Ohùn Àgbáyé ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà ní àsìkò tí àwọn ń fi aṣọ pénpé ro oko ọba. Ní ètò ìtàkùrọ̀sọ wọn, wọ́n gbé orí yìn fún ìpolongo Ohùn Àgbáyé tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi tí ó mú àwọn wà láyé.
Berhan Taye, atọ́kùn ìtàkùrọ̀sọ, bi ẹgbẹ́ yìí ní ìbéèrè ìrírí wọn ní inú túbú. Bí wọ́n ti ṣe sọ, iná amọ́roro ìtàgé wálẹ̀ díẹ̀. Ohùn-un wọn mú kí iyàrá ètò pa lọ́lọ́.
Abel Wabella, alákòóso Ohùn Àgbáyé ní ‘ Èdè Amharic , kò fi etí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ kan gbọ́ràn já geere mọ́n láti ara ìjìyà oró tí ó jẹ́ nítorí pé ó kọ̀ láti ti ọwọ́ bọ ìwé ìjẹ́wọ́.
Atnaf Berhane rántí wípé òún jẹ ìyà oró di aago méjì òru tí òún padà sí lẹ́yìn oorun díẹ̀.
Ọ̀kan lára àwọn agbófinró tí ó mú Zelalem Kibret ti fi ìgbà kan rí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Kibret ní Ifásitì tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ olùkọ́.
Jomanex Kasaye náà ṣe ìrántí ìwàyáìjà ọpọlọ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìrònú ìfìlú Ethiopia sílẹ̀ kí wọ́n ó tó fi ọwọ́ òfin mú àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ — ìrora àìlágbára — ìlàkàkà ọkàn àti àìfẹ̀dọ̀lórí òróòró àti ìbẹ̀rù wípé àwọn ọ̀rẹ́ òhun ò ní jáde láàyè.
Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, àwọn akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 sọ wípé: “A kò kí ń ṣe ẹni tí ó ní okun tàbí ìgboyà.. inúu wa dùn nítorí wípé a fún àwọn ènìyàn mìíràn ní ìmísí ni.”
Síbẹ̀, akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 ṣe àtúnlò ìfẹ́-ìlú-ẹni nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Ó gba ìgboyà láti fẹ́ràn ìlú ẹni pàápàá lẹ́yìn ìjìyà nítorí wípé a sọ̀rọ̀ síta.
Oníròyìn ọmọ Uganda Charles Onyango-Obbo, tí òun náà wà ní FIFA, mẹ́nu ba òwe Igbo tí gbajúgbajà òǹkọ̀wée nì Chinua Achebe mú di mímọ́ tí ó sọ wípé:
Níwọ̀n ìgbà tí òde ti já ọgbọ́n àtamátàsè, ẹyẹ Eneke náà ti kọ́ fífò láì bà.
Ní àkótán, ohun tí ó fẹ́ sọ ní wípé láti mú ayélujára wà ní ipò ọ̀fẹ́ àti ààbò, àwọn tí ó ń jà fún èyí nílò láti wá ọgbọ́n mìíràn dá.
Àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ tí ó ń lé iwájú nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ìlú-Gúúsù-Aṣálẹ̀-Sàhárà àti káríayé kò gbọdọ̀ ṣe aláì máà wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣ'àdá lórí ọ̀ràn yìí. Pẹ̀lú agbára àti àjọṣe wa, ẹ̀rọ-ayélujára yóò di ibi òmìnira fún ìtẹ̀síwájú ìjọba àwa-arawa.