Mọ àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ọdún 2019

Àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ọdún 2019 [Àkópọ̀ àwòrán láti ọwọ́ọ Nwachukwu Egbunike].

Nàìjíríà, orílẹ̀-èdè tí ó ní ènìyàn tí ó pọ̀ jù ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, yóò di ìbò ipò ààrẹ ní ọjọ́ 16, oṣù 2019. Bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-wípé àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ t'ó 73, eré Àpáta Agbára – ibùjókòó ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà – yóò wáyé ní àárín-in ẹgbẹ́ olóṣèlú méjì tí ó ti ń figagbága ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́ àti àwọn òǹdíje tí a pè ní “agbára ìkẹta”, ìyẹn àwọn ẹgbẹ́ a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Muhammad Buhari, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Creative Commons.

Ẹgbẹ́ méjèèjì tí ó gbajúmọ̀ jù lọ, Ìpéjọ Ìlọsíwájú Gbogboògbò APC àti Ẹgbẹ́-olóṣèlú Ìjọba-àwa-arawa PDP, láì ṣe àní-àní, yóò tari òǹdíje wọn sí gbangba wálíà:

Muhammadu Buhari

Ààrẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ó jẹ́ òǹdíje lábẹ́ àsíá APC, Buhari ló jáwé olúborí nínú ìbò ààrẹ ti ọdún 2011 tí ààrẹ ìgbà kan Goodluck Jónátánì sí pàdánù. Nítorí irú ènìyàn tí Buhari ń ṣe àti èrò wípé yóò gbógun ti ìjẹgúdújẹrá àti ìgbáwọlẹ̀ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò Boko Haram ni àwọn ará ìlú fi gbé e sórí àlééfà.

Síbẹ̀, lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, ààbò ẹ̀mí kò sí pẹ̀lú ìkọlù láàárín darandaran àti àgbẹ̀ bí àwọn darandaran láti àríwá ṣe ń wọ gúúsù láti wá koríko fún ẹran ọ̀sìn-in wọn. Bákan náà, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti wó lulẹ̀ nínú ìṣàkóso ìjọba rẹ̀, pẹ̀lú àìjẹ̀yà àti ìṣowó-ìlú-mọ̀kumọ̀ku ní ibi gíga nínú ìjọba.

Atiku Abubakar [Àwòrán Ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé Ilé-iṣẹ́ ìpolongo].

Atiku Abubakar

Abubakar ni igbá-kejì ààrẹ ìgbà kan àti òǹdíje lábẹ́ àsíá PDP. Ó ti gbìyànjú sẹ́yìn láti di ààrẹ àmọ́ orí kò ṣe ní oore. Bíótiwùkíórí, ìpolongo rẹ̀ jẹ́ ìgbàwọlé nítorí ìparí ìjà tí ó wà ní àárín òun àti ọ̀gáa rẹ̀, Ààrẹ ìgbà kan rí Olusegun Obasanjo — tí ó sọ wípé ìṣàkóso ìjọba Buhari kùnà. Gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́, Abubakar ni ó ṣe bònkárí ìsọhun-ìjọba-di-àdáni àti títa ọ̀kẹ́ àìmọye ilé iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti ìjọba tí kò pa owó sí àpò ìjọba.

Àwọn mìíràn tí ó ní ìrètí sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ni:

Oby Ezekwesili [Àwòrán tí àwọn alágbèékalẹ̀ ìpolongo tari síta]

Obiageli [Oby] Ezekwesili 

Ezekwesili, obìrin kan ṣoṣo tí ó ń du ipò nínú eré ìbò sísá ti ọdún tí a wà yìí, ti ṣe mínísítà ọrọ̀ líle inú-ilẹ̀ àti ètò ẹ̀kọ́ ní àsìkò ìjọba Olusegun Obasanjo ní àárín ọdún 1999 sí 2007. Ó sì ti ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ààrẹ Ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé ẹ̀ka ti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ìgbà kan láti oṣù Igbe ọdún 2007 sí oṣù Igbe ọdún 2012. Ezekwesili ti ṣe bẹbẹ nínú akitiyan ìdásílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́-bìnrin 200 tí ọmọ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfo Ẹlẹ́sìn ìmale jí gbé ní ọdún 2014. Ó jẹ́ ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ Ìpolongo #BringBackOurGirls (BBOG). Bákan náà ni ó jẹ́ òǹdíje sí ipò ààrẹ ní abẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú Allied Congress Party ti Nàìjíríà.

Kingsley Moghalu [Àwòrán láti ibùdó ìpolongo].

Kingsley Moghalu

Moghalu jẹ́ onímọ̀ nínú ìdókòwò àgbáyé àti òfin gbogbo ènìyàn ní ilé ìwé Òfin àti Ọgbọ́n Fletcher ní Ifásitì Tufts ní Massachusetts, USA. Moghalu ti ṣiṣẹ́ rí ní United Nations láti ọdún 1992 sí 2008. Ó ti ṣe igbá-kejì gómìnà Ilé Ìfowópamọ́ Àgbà ti Nàìjíríà láti ọdún 2009 sí 2014, níbi tí “ó ti tukọ̀ ọ àwọn àgbà iṣẹ́ àtúnṣe nínú ètò ìkówóoamọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ìgbà tí ọrọ̀ Ajé àgbáyé ti ṣe òjòjò tán.” Òun ni òǹdíje ní abẹ́ àsíá Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Ìtẹ̀síwájú Ọ̀dọ́ – YPP.

Ọmọ́yẹlé Sowóre [Àwòrán ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ní orí  CNBCAfrica, ní ọjọ́ 13, oṣù Ọ̀p, ọdún 2018].

Omoyole Sowore

Sowore ni olùdásílẹ̀ àti atẹ̀wéjáde SaharaReporters (SR), ilé-iṣẹ́ oníròyìn aṣèwádìí orí-ayélujára. SR ni à ń pè ní Wikileaks Ilé Adúláwọ̀. Ajà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn yìí ń jáde lábẹ́ àsíá African Action Congress.

Aré ti ń lọ fún ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Buhari àti Abubakar ni afigagbága ìdíje ìbò aré yìí. Àwọn méjèèjì ti ń figagbága nínú ìbò Nàìjíríà ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Ní ọ̀nà kejì, Ezekwesili, Moghalu, Sowore, àwọn “agbára ìkẹ́ta”, jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó ń wọ inú ètò ìṣèlú fún ìgbà àkọ́kọ́.

Iṣẹ́ ìṣàkóso Buhari ọdún mẹ́ta ni yóò “gbè é” lẹ́yìn àti pé yóò bá ìfi Nàìjíríà sí ipò olú orílẹ̀-èdè tí ìṣẹ́ ti pọ̀ jù. Ìwé ìròyìn Punch ṣe ìfojúsùn “ìpèsípò” gẹ́gẹ́ bí “àìròtẹ́lẹ̀ ” àti pé ó ti pín ìlú yẹ́bẹyẹ̀bẹ. Ètò ìgbógunti ìwà àjẹbánu rẹ̀ fì sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ìgbésẹ̀ tí ó gbé láì pẹ́ yìí láti ṣe ìgbẹ́jọ́ Adájọ́ Àgbà orílẹ̀ èdè — tí ó ti sún mọ́ ìbò ààrẹ — ni Àjọ Adájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà  Nigerian Bar Association pè ní “àwòṣe ìkọlù ní lemọ́lemọ́ ní orí àwọn àgbà ẹ̀ka ìjọba méjèèjì tí-kò-gbáralé ìjọba” ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari.

Abubakar, ní ọ̀nà kejì, ń dúró lórí “ìgbẹ́kẹ̀lé” àwọn “ẹgbẹlẹmùkù okòwò tí ó ní èrè lóríi rẹ̀”.  Bíótiwùkíórí, ó ní láti bá agbára ìwàlóríoyè afigagbága rẹ̀ takọ̀ngbọ̀n.

Ẹni yòówù tí ó bá gbégbá-orókè nínú ìdíje sí ipò ààrẹ ọdún 2019 ní iṣẹ́ ìmúgbòòrò ọrọ̀ Ajé, ààbò ní àárín ìlú, àtúntò agbára àti ìmúkárí agbára, àti ìṣèlú elẹ́yàmẹyà làti ṣe.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.